Ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o fipa baayan lo pọ l’Ekoo yoo dara ẹ lẹbi – Sanwo-Olu

 Jide Alabi

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti fidi ẹ mulẹ pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o fipa baayan lo pọ, ijọba oun yoo fija nla jẹ ẹ labẹ ofin.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni gomina sọrọ ọhun nigba ti wọn fun un labọ iṣẹ iwadii igbimọ ti iyawo ẹ, Dokita Ibijọkẹ Sanwo-Olu, gbe kalẹ lati wa ọna abayọ si iwa ifipa-banilopọ, lilo ọmọde nilokulo ati ṣiṣe-obinrin-niṣekuṣe.

Lasiko ọhun ni Gomina Sanwo-Olu sọ pe ijọba oun ko ni i fọwọ kekere mu iru iwa ọdaran bẹẹ, ati pe ẹni ti wọn  ba ti mu l’Ekoo pe o fipa baayan sun, iru ẹni bẹẹ yoo dara ẹ lẹbi nla.

O ni, “Ohun idunnu ni abajade iṣẹ ti igbimọ yii ṣe. Igbagbọ mi ni pe iru igbesẹ yii gan-an ni yoo fun awọn eeyan lanfaani lati jade sọ tẹnu wọn, ti iru isẹlẹ bẹẹ ba ṣẹlẹ si wọn.

“Enikẹni tọwọ ba tẹ, niṣe la maa fimu iru wọn danrin. O ṣe diẹ ti ọfiisi iyawo gomina l’Ekoo ti gbe igbimọ ọhun kalẹ lati wa ọna abayọ si bi iru awon iwa buruku bẹẹ yoo ṣe dinku tabi dopin lawujọ.”

Leave a Reply