Ẹnu-ọna baaluu lọwọ ti ba awọn ọmọge meji yii, ayederu iwe irinna ni wọn feẹ lo

Faith Adebọla, Eko

 

 

Ahamọ awọn agbofinro to n ri si iwọle ati ijade kuro lorileede wa, awọn Imigireṣan, ni Kẹhinde Babalọla ati Adebayọ Kọlapọ Kazeem wa bayii, ẹnu ọna baaluu ti wọn fẹẹ dọgbọn wọ sa lọ sorileede Egypt lọwọ ti tẹ wọn, latari ayederu iwe irinna ti wọn gbe dani.

Owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, lọwọ to awọn ọmọge meji naa ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed, n’Ikẹja, ipinlẹ Eko. Ẹni ọdun mẹrindinlọgọn lawọn mejeeji.

Alukoro fun ileeṣẹ Imigireṣan, Ọgbẹni Sunday James, ṣalaye ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ pe ilu Cairo, ti i ṣe olu-ilu orileede Egypt, lawọn obinrin yii sanwo pe awọn n lọ, wọn ti gba fisa, wọn si ti sanwo baaluu, koda wọn ti gba nọmba aaye ijokoo ninu baaluu to fẹẹ gbera laaarọ yii.

James ni ko sẹni to mọ ọgbọn tawọn afurasi mejeeji naa da si i, ẹṣọ Imigireṣan kan lo fura si wọn bi wọn ṣe n gun akaba lati wọnu baaluu ọhun, ni wọn ba ni ki wọn jẹ kawọn yẹ iwe wọn wo lẹẹkan si i, ibẹ laṣiiri ti tu pe ko sibi ti wọn ti lu iwe naa lontẹ to yẹ, igba ti wọn si wo nọmba pasipọọtu (iwe irinna) ọwọ wọn, ti wọn ṣayewo ẹ lori ẹrọ kọmputa awọn áṣọbode, kia ni kọmputa fihan pe ayederu (fake) iwe irinna ni wọn gbe dani, tori fọto ọkunrin ati orukọ to yatọ lo han loju ẹrọ kọmputa to n ṣayẹwo, gbogbo

Leave a Reply