Faith Adebọla, Eko
O kere tan, awọn afurasi ọdaran mẹwaa ni wọn ti n gbatẹgun lakata awọn ẹṣọ Sifu Difẹnsi, (Nigeria Security and Civil Defence Corps, NSCDC), ẹka ti ipinlẹ Eko bayii. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn n jale epo rọbi, epo bẹntiroolu (petrol) ati diisu (diesel), wọn n fi i ṣowo lai gbaṣẹ.
Orukọ awọn mẹwẹẹwa ni: Moses Ajimiṣan, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, Olumide Ikuyinmi, ẹni ọdun mẹtalelaaadọta, Pius Ayẹni, ẹni ọdun marundinlaaadọta, Monday Otuagomah, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, Okriko Ebi, ẹni ọdun marundinlaaadọta ati Bibabi Males, ẹni ogoji ọdun. Awọn to ku ni Idowu Ẹkundayọ, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, Maurice Blessing ati Wisdom Blessing tawọn mejeeji jẹ ẹni ọgbọn ọdun, ati Barry Ọmọṣẹyẹ, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta.
Ninu ọrọ ti Kọmandanti Sifu Difẹnsi, Ọgbẹni Paul Ayẹni, sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), lori iṣẹlẹ yii, o ni epo diisu bii lita ẹgbẹrun lọna ọgọta (60,000 litres) tawọn afurasi ọdaran naa ji wa, lawọn ka mọ wọn lọwọ ni nnkan bii aago meji ọganjọ oru, ori omi lawọn kọlọransi naa fẹẹ gba sa lọ.
Ayẹni sọ pe ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, lọwọ kọkọ ba diẹ lara wọn, lẹyin itọpinpin ati iwadii lawọn agbofinro tun ri awọn kan mu, ti wọn fi di mẹwaa. O lawọn ọmọ ogun ori omi ilẹ wa ṣeranlọwọ fawọn Sifu Difẹnsi, wọn yọnda ọkọ oju ọmi wọn (Nigeria Navy Ship) tawọn lo.
Gbogbo awọn tọwọ ba yii ti n ṣalaye ara wọn fawọn agbofinro to n ṣewadii, lẹyin iwadii yii lo wọn yoo foju wọn bale-ẹjọ.