Epo ti Emmanuel ko sinu mọto lo gbina lojiji to fi jona ku n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni arakunrin dẹrẹba ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Emmanuel, pade iku ojiji lagbegbe Egbejila, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, epo bẹtiroolu lo lọọ ra to ko sinu ọkọ ti ọkọ fi gbana.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, fi sita lowurọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ni iṣẹlẹ buruku naa waye ni ileesẹ ti wọn ti n pọnmi ta kan ti orukọ rẹ n jẹ Softfort Table Water, to wa ni Block 2, Ọbanisuwa, Egbejila, l’Opopona papakọ ofurufu Ilọrin. O ni Emmanuel ni dẹrẹba wọn,  o lọ sile-epo lati lọọ ra epo bẹtiroolu sinu galọọnu, lẹyin to ra a tan lo ko o sinu ọkọ ayọkọlẹ Premiere kan to ni nọmba: LSR966GD, to o si yi gbogbo windo ọkọ naa soke. Ṣugbọn lojiji ni ọkọ ọhun gbina lasiko to de ẹnu geeti ileeṣẹ naa, to si jona mọ’nu ọkọ.

O tẹsiwaju pe ooru lo pọ ju ti epo ọhun fi gbana. Ajọ panapana ti yọ oku rẹ ninu ọkọ, wọn si ti gbe e le ọga rẹ to ni ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Surajudeen, lọwọ.

Adari ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, kẹdun pẹlu mọlẹbi oloogbe fun bi wọn ṣe padanu ọkan lara wọn, bakan naa lo rọ gbogbo olugbe Kwara lati maa lo gbogbo ohun to ba le daabo bo ẹmi ati dukia wọn.

Leave a Reply