Erin wo! Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, ti waja

Ọlawale Ajao, Ibadan
Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, ti darapọ mọ awọn baba nla rẹ lẹni ọdun mẹtalelọgọrin.
Alẹ ọjọ Ẹti ni Kabiyesi papoda ni ọsibitu Afẹ Babalọla University Teaching Hospital, to wa niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, lẹyin aisan ranpẹ.
Wọn ti gbe oku ọba nla naa pada siluu Ọyọ, ti etutu gbogbo to yẹ nipa ipapoda ọba naa si ti bẹrẹ.
Ọba Adeyẹmi lo ti i pẹ lori oye ju ninu awọn ọba to jẹ ni ilu naa. Ọdun mejilelaaadọta lo lo lori itẹ.

Leave a Reply