Monisola Saka
Idunnu ṣubu lu ayọ fun mọlẹbi awọn eeyan mẹtalelogun to ṣẹku nigbekun awọn agbebọn to da tireeni to n lọ si Kaduna lati Abuja ni bii oṣu meje sẹyin duro. Ọjọ nla ni ọjọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, jẹ fun awọn eeyan naa atawọn ẹbi wọn. Ariwo, ‘mo yọ, mo yọ’ ni wọn n ke nitori ọpọ ninu wọn lo ti sọ ireti nu pe ibi tawọn maa ṣegbe si lawọn de duro yẹn.
Ni kete ti ọga awọn ologun, Lucky Irabor, kede itusilẹ lawọn eeyan naa n fo fayọ. O ṣalaye pe gbese ọpẹ nla ni orilẹ-ede yii jẹ awọn ileeṣẹ ologun fun aṣeyọri nla naa.
Ninu atẹjade ti Akọwe igbimọ ti olori ileeṣẹ ologun gbe kalẹ, Ọjọgbọn Usman Yusuf, lo ti sọ pe, “Pẹlu inu didun ni mo fi n kede fun gbogbo awọn ọmọ Naijiria pe, lonii, Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni deede aago mẹrin irọlẹ geerege ni awọn igbimọ ẹlẹni meje kan ti Ọgagun Irabor gbe kalẹ, ṣe ọna bi awọn eeyan mẹtalelogun to ṣẹku sakata awọn ikọ mujẹmujẹ Boko Haram ti wọn dena de ọkọ oju irin to n lọ siluu Kaduna lati Abuja lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2022 ṣe jade.
Ka ranti pe, latinu oṣu Kẹta, ọdun yii, tawọn eeyan ọhun ti wa lahaamọ awọn agbesunmọmi yii ni wọn ti n fi wọn silẹ lọkọọkan ejeeji.
“Orilẹ-ede yii si jẹ awọn ọmọ ogun Naijiria labẹ iṣakoso Ọgagun Irabor ni gbese ọpẹ nla fun gbogbo akitiyan ati ọgbọn to ta lati ri i daju pe a ṣe iṣẹ yii laṣẹyọri lati ibẹrẹ de opin.
Bẹẹ la dupẹ pataki fawọn ileeṣẹ eleto aabo pata ati ileeṣẹ eto irinna fun ipa ribiribi ti wọn ko”.
Ọkan ninu awọn olori ẹbi awọn to wa nigbekun Boko Haram yii, Dokita Abdulfatai Jimoh, loun o le sọ bi inu oun ṣe dun to pẹlu bi wọn ṣe tu awọn eeyan naa silẹ. O dupẹ pupọ lọwọ ijọba apapọ ati ileeṣẹ ologun ti wọn mu ki ẹrin tun pa ẹẹkẹ awọn mọlẹbi ti wọn ti sọ ireti nu ọhun.