Ero rẹpẹtẹ ha saginju ni Kogi, ẹsẹ reluwee to gbe wọn lo yẹ lori ere

 Faith Adebola

Ẹni ori yọ o dile, lọrọ di fawọn ero atawọn oṣiṣẹ ọkọ reluwee ilẹ wa to n na ọna Warri, nipinlẹ Delta, si Itakpe, nipinlẹ Kogi, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejilelogun, oṣu Ki-in-ni yii, nigba ti taya reluwee naa yẹ kuro loju ọna rẹ, to si mori le inu igbo, lo ba ja awọn ero naa saarin aginju igbo kijikiji, nipinlẹ Kogi.

Bawọn ero bii mejidinlaaadọjọ ti wọn ni reluwee ọhun ko, atawon bii mejidinlogoji ti wọn n ṣiṣẹ ninu ẹ ṣe n dupẹ lọwọ Eleduwa to ko wọn yọ lọwọ iku ojiji, bẹẹ ni ibẹrubojo, aibalẹ-ọkan ati ipaya gba ọkan wọn, tori ewu awọn afẹmiṣofo agbebọn atawọn ajinigbe ti wọn n ṣoṣẹ kaakiri awọn igbo kijikiji ilẹ wa, bẹẹ ko si ọna mọto tabi ọkada ninu aginju ti reluwee naa da nu si.

A gbọ pe reluwee yii gbera niluu Warri, laaarọ Sannde, amọ ni nnkan bii aago kan ọsan ni ijamba naa waye laarin Ajaokuta si ilu Itakpe.

Ọga agba ileeṣẹ reluwee ilẹ wa, ìyẹn Nigerian Railway Corporation (NRC), Ọgbẹni Fidet Okhiria, lasiko to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lawọn ti ṣeto ki reluwee mi-in lọọ pade awọn ero to ha saginju naa, ki wọn le ko awọn atẹru wọn kuro nibi ewu.

Bakan naa lo lawọn ti bẹrẹ igbesẹ lẹyẹ-o-sọka lati wọ reluwee to fọna silẹ, to mori legbo, naa kuro nibi to ti dabuu ọna, ṣugbọn o ni reluwee mi-in ko ni i le gba ọna ọhun kọja titi tawọn yoo fi ṣayẹwo si ohun to ṣokunfa ijamba yii.

Latari iṣẹlẹ yii, Alaroye gbọ pe ileeṣẹ reluwee ilẹ wa ti so igbokegbodo irinna reluwee ọna Warri si Itakpe rọ na, wọn si ti fagi le itolẹsẹẹsẹ irinna reluwee to ti wa nilẹ tẹlẹ.

Ninu atẹjade kan ti NRC fi lede nipasẹ oluṣekokaari irinna reluwee Warri si Itakpe, Ọgbẹni Sanni Abdulganiyu, laṣaalẹ ọjọ Sannde naa, wọn ni igbesẹ yii pọn dandan ki wọn le raaye ṣatunṣe si oju irin reluwee naa, ki wọn si le tubọ pese aabo to peye.

O lawọn dupẹ pe ko sẹni to ku tabi fara pa ninu ijamba reluwee to waye naa.

Ba a ṣe gbọ, ọkọ reluwee WITS 01 to n lọ lati Warri si Itakpe yii kan naa lawọn afurasi agbebọn kan ṣakọlu sawọn ero to fẹẹ wọ ọ lagbagbe Igueben, ipinlẹ Edo, lọsẹ meji sẹyin, ti wọn si ji eyi to ju ogun lọ ninu wọn, nigba ti ọpọ fara pa yannayanna nibi ti wọn ti n sa asala fẹmi-in wọn.

Leave a Reply