Ero rẹpẹtẹ lẹyin Ọṣinbajo lasiko to ṣabẹwo si Ogbomọṣọ, Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bii omi lero n wọ tẹle Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, to ṣabẹwo ‘ẹ ku ara fẹraku’ si mọlẹbi Sọun Ogbomọṣọ ati gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Ọtunba Alao Akala pẹlu awọn mọlẹbi Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, to waja laipẹ yii.

Ilu Ogbomọṣọ ni Ọṣinbajo kọkọ lọ, ti Gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde atawọn eeyan nla nla mi-in si kọwọọrin pẹlu rẹ. Ariwo, ‘Ọṣinbajo, aarẹ wa ni 2023’, ‘A nifẹẹ rẹ’, ‘Iwọ la maa dibo fun lọdun to n bọ’ ati bẹẹ beẹ lọ ni awọn eeyan naa n pa pẹlu akọle oriṣiiriṣii ti wọn gbe lọwọ. Bẹẹ ni wọn n kọrin ọlọkan-o-jọkan ninu aṣọ ẹgbẹjọda ti wọn wọ.

Ọṣinbajo naa duro sẹnu ọna ọkọ to gbe e wa, to si n ki awọn omilẹgbẹ eeyan to n tẹle ọkọ rẹ bo ṣe wọnu

ilu naa. Bẹẹ lo n fi tayọtayọ juwọ si wọn ninnu mọto to jokoo si.

Bakan naa ni Igbakeji Aarẹ ati Gomina Ṣeyi Makinde darapọ mọ awọn eeyan ninu ijọ Onitẹbọmi akọkọ niluu Ogbomọṣọ, fun ẹyẹ ti wọn ṣe fun Ọba Ọladunni Oyewumi.

Bakan naa lo ṣabẹwo si wọn nile Oloogbe Alao Akala. Lẹyin to kuro nibẹ lo gba ilu Ibadan lọ. Ile Olubadan ilẹ Ibadan tẹlẹ, Ọba Saliu Adetunji, lo balẹ si lati ki wọn ku aṣẹyinde kabiyesi to waja.

Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ṣapejuwe Olubadan to waja gẹgẹ bii oloootọ eeyan, ẹni to ṣee fọkan tan.

Lasiko abẹwo ibanikẹdun to ṣe sile wọn to wa laduugbo Popoyemọja, n’Ibadan, lo ti sọrọ naa nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde.

Ọṣinbajo, ẹni ti Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan, kọwọọrin pẹlu ẹ, lawọn igbimọ agba ilẹ Ibadan (CCII), Omọọba Bisi Adeaga; awọn ijoye atawọn Mọgaji ilẹ Ibadan pẹlu Olori Rashidat Adetunji ti i ṣe aya oloogbe ọba naa gba lalejo.

Nigba to n fi ẹdun ọkan rẹ han nipa ipapoda Olubadan to gbesẹ naa, Ọṣinbajo sọ pe ‘mo wa sibi lorukọ Aarẹ Muhammadu Buhari lati kẹdun pẹlu yin nipa ipapoda baba wa to waja.

“Oloootọ ni baba. Latigba ti wọn ti bẹrẹ ìgbésí aye wọn, titi dori iṣẹ wọn gẹgẹ bíi oniṣowo to n gbe awọn Olorin jade ati titi ti wọn fi gori itẹ ọba. Nnkan ti wọn ba maa ṣe ni wọn maa sọ.

“Baba fi ogun silẹ. Ogun ti wọn fi silẹ ki i ṣe ogun ile tabi mọto, bi ko ṣe ogun orukọ rere. Orukọ rere ti wọn fi silẹ yii ni gbogbo ayé fi n sọrọ wọn lẹyin iku wọn yii. Bẹẹ miiran yoo si maa sọ ọ titi aye.’’

Nigba to n fẹmi imoore han nipa abẹwo naa lorukọ idile Adetunji, ọmọkunrin ọba to doloogbe naa, Ọmọọba Raheem Adetunji, dupẹ lọwọ Igbakeji Aarẹ fun abẹwo naa.

Leave a Reply