Eroja ara faanu ti Rasheed ji l’Oṣogbo ti sọ ọ dero ọgba ẹwọn

Florence Babaṣọla

Rasheed Kọla, ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn ni awọn ọlọpaa ıpinlẹ Ọṣun ti gbe lọ sile ẹjọ Majistreeti kan niluu Oṣogbo bayii lori ẹsun ole jija.

Gẹgẹ bi agbefọba, Inspẹkitọ Adeoye Kayọde, ṣe sọ ni kootu, aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni olujẹjọ lọ si sọọbu Azeez Fatai to wa lagbegbe Basi Bankọle, ni Oke-Onitea, niluu Oṣogbo.

Nigba to debẹ, o fọ sọọbu Afeez, o si ji faanu ti wọn maa n so mọ ori aja meji (ceiling fans), kọili faanu kan, ayọọnu meji, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Apapọ gbogbo owo awọn nnkan ti Rasheed ji ni sọọbu Azeez jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọta naira, eleyii ti agbefọba ṣalaye pe o lodi si abala irinwo o din mẹwaa ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.

Rasheed ko jẹ ji ọrọ naa falẹ rara, kia lo ti sọ pe oun jẹbi ẹsun ti awọn ọlọpaa fi kan oun, o si rọ adajọ pe ko ṣaanu oun nitori igba akọkọ leleyii ti oun yoo hu iru iwa bẹẹ, ati pe oun ti pinnu lati ma ṣẹ ṣan iru aṣọ bẹẹ ṣoro mọ laelae.

Adajọ Ọpẹyẹmi Badmus paṣẹ pe ki Rasheed lọọ fi aṣọ penpe roko ọba fun odidi oṣu mẹfa lai fi aaye faini kankan silẹ fun un.

Leave a Reply