Ẹru kan wa to n ba mi o

Mo fẹ ki a jọ yẹ awọn kinni wọnyi wo, ko ma da bii pe emi nikan ni mo n pe ara mi ni ọlọgbọn aye, tabi ko ma jẹ ironu aṣiwere lo wa lori mi ti mo n pe ni ironu gidi. Orilẹ-ede wa Naijiria yii ni ileeṣẹ ti wọn ti n fọ epo rọbi (refineries) mẹta nla nla. Wọn ni ni Warri; wọn ni ni Pọta, wọn si ni ni Kaduna. Lojoojumọ, awọn ileeṣẹ ifọpo yii, ti wọn ba fọ epo to yẹ ki wọn fọ, Kaduna aa fọ koroba epo aadọfa ẹgbẹrun (110,000); eyi to wa ni Pọta yoo fọ marundinlaaadoje ẹgbẹrun (125,000), eyi to si wa ni Warri yoo fọ ẹgbẹrun lọna mẹwaalenigba (210,000). Eyi ni pe, lapapọ, iye to yẹ ki awọn ileeṣẹ ifọpo mẹtẹẹta yii fọ lojumọ fun wa ni ẹgbẹrun lọna ojilenirinwo ati marun-un (445,000). Awọn ileeṣẹ ifọpo keekeekee mi-in tun wa o, ṣugbọn ẹ ma jẹ ka ka tiwọn mọ ọn. Ẹ jẹ ka duro lori mẹta yii.

E jọwọ, mo fẹ ki ẹ maa fi oye ba ọrọ yii lọ o. Ni ojumọ kan, iye koroba epo ti a n lo ni Naijira wa yii jẹ okoolenirinwo ati mẹjọ ẹgbẹrun (428, 000). Eyi tumọ si pe ti ohun gbogbo ba lọ bo ti yẹ ko lọ, ti ijọba Naijiria ba ṣeto, ti wọn si lo awọn ile-ifọpo wọn lati wọn fọ epo fun wa, lẹyin ti a ba lo eyi ti a oo lo tan, Naijiria ṣi maa ni ẹgbẹrun mẹtala  (13,000) koroba epo ti wọn ti fọ nilẹ lojoojumọ. Eyi ko mọ epo tawọn ile-ifọpo keekee to ku n fọ, awọn ileeṣẹ ifọpo nla nikan ni mo n sọ.  Bi ti Naijiria ti ri niyi.

Ṣugbọn orilẹ-ede kan naa wa lẹgbẹẹ wa nibi to n jẹ Nijee (Niger Republic), awọn naa ni ileeṣẹ ifọpo kan to n fọ ogun ẹgbẹrun (20,000) koroba epo lojumọ kan. Wọn waa sọ pe wọn ki i lo epo tiwọn yii tan, ni Naijiria ba ko iwe jọ, wọn lawọn aa maa ra epo lati Nijee, ẹgbẹrun mẹẹẹdogun koroba ni wọn si maa ra lọjọ kan, nitori wọn ni ẹgbẹrun marun-un pere lawọn n lo ninu epo ti wọn ba fọ. Lọrọ kan, orilẹ-ede Nijee ni Naijiria ti fẹẹ maa ra epo wale bayii o.

Ọrọ naa ba mi ninu jẹ ju bi mo ti ro pe yoo ba mi ninu jẹ lọ, ṣe mo ti mọ ọrọ yii tẹlẹ, mo si ti sọrọ lori ẹ ri. Ṣugbọn pe ijọba ti a ni lode bayii kuku ba orukọ Naijiria jẹ kanlẹ-kanlẹ bii eyi, ti wọn sọ wa di ọmọ akotileta loju gbogbo aye, ati alailero agbalagba, ohun ti n ko ro pe o le ka mi lara to bayii ni. Abi bawo ni orilẹ-ede to le fọ ẹgbẹẹgbẹrun koroba epo lọjọ kan yoo ṣe maa lọọ ra epo lọdọ awọn to n fọ ogun ẹgbẹrun pere. Ki lawọn ti wọn n ṣejọba sọ aye wa da yii na! Ṣugbọn ọrọ naa le ju bẹẹ lọ. O le ju bi awọn eeyan ti ro o lọ. Ohun ti a n ri ọtọ, ohun to n ṣẹle gan-an, ọtọ; awọn ti wọn ba ni arojinlẹ ọrọ yii nikan lo ye daadaa. Gbogbo ẹya to ku ni Naijiria yii pata ti ha sọwọ Fulani, ibi ti a oo ti bọ lọwọ wọn ni mo n wo ti ko ti i ye mi. Bi a ba tilẹ fẹẹ yọ paapaa, awọn oloṣẹlu ole ta a ni ko ni i jẹ ko ṣee ṣe fun wa.

Nigba ti ọrọ yii kọkọ bẹrẹ, ti ijọba wa ni oun fẹẹ la ọna reluwee lati ilẹ yii lọ si Maradi, ti i ṣe ẹnubode ilẹ Hausa ati orilẹ-ede Nijee, mo pariwo gidi gan-an ni, nitori mo mọ pe ẹtan lo wa nidii ẹ. Lẹyin naa ni ijọba yii kede pe nitori ki awọn le lọọ maa fọ epo lati Nijee ni awọn ṣe fẹẹ la ọna reluwee, nigba to si ya ni wọn tun ni awọn fẹẹ lọọ maa ra epo lati ibẹ ni. Wọn ṣa n sọ kotokoto loriṣiiriṣii. Ṣugbọn mo ri wọn nigba naa o, mo si pe akiyesi awọn eeyan wa si i. Mo sọrọ naa loju iwe ti mo n kọ nibi yii, ṣugbọn gẹgẹ bi awọn eeyan wa ti a n ba sọrọ ṣe maa n ṣe, eebu lawọn mi-in n bu mi, ti wọn ni mo fẹẹ da ilu ru, eto daadaa nijọba fẹẹ ṣe fawọn, ki n ma fi temi di tiwọn lọwọ. Ironu ọrọ awọn eeyan wa ki i ju ti APC ati PDP pẹlu ọrọ oṣelu wọn lọ, wọn ki i ronu lori aburu to n yi wọn ka rara. Abi ninu eyi ti ijọba Buhari ṣe yii, ewo lo ni oore ninu fun wọn o!

Ohun ti mo sọ nigba naa, ti ma a tun sọ nibi yii ni pe, gbogbo ọna pata ni ijọba awọn Buhari n wa lati mu idagbasoke ba orilẹ-ede Nijee, nitori ‘ihin-ile-ọhun-ile’ ni ibẹ jẹ fun wọn. Nnkan ọrọ aje ati awọn ohun alumọọni wa ni wọn fẹẹ fi tun aye awọn ara Nijee ṣe. Ni orilẹ-ede Nijee yii, ọpọ awọn eeyan ni wọn wa nibẹ to jẹ Naijiria tiwa nibi ni awọn ibatan wọn wa. Awọn ile mi-in wa ni Nijee to jẹ apa kan ni Nijee, apa keji ni Naijiria ni. Wọn aa jọ maa rin wọ inu oko ara wọn, wọn aa si jọọ maa gbe inu awọn abule wọnyi. Ọpọ ọna lo wa nibẹ ti wọn le ba wọ orilẹ-ede wa yii lai ni i gba ẹnubode rara. Ati pe nigba ti ẹ ba ri ọpọ ọmọ Nijee yii, ẹ ko ni i mọ boya Hausa tabi Fulani tiwa ni wọn ni tabi tawọn ti Nijee, nigba to jẹ bakan naa ni wọn. Bakan naa ni wọn jọ n ṣe, ede kan naa lo si wa lẹnu wọn.

Ko too di pe awọn oyinbo de ti wọn pin awọn orilẹ-ede yii, ibi kan naa lawọn Hausa tiwa ati tawọn ti Nijee yi n gbe. Bi ẹ ba si wo o daadaa, orukọ kan naa lawa mejeeji jọ n jẹ. Odo Ọya ti a n pe ni Naija (Niger) ti wọn fi sọ orukọ tiwa ni Naijiria naa lo wa ni orilẹ-ede Nijee (Niger lede Faranse), eyi lo si ṣe jẹ pe “Niger” “Niger” lorukọ wa, ti ọkan jẹ ni ede oyinbo, ti ekeji si jẹ ti ede Faranse. Awọn Hausa ati Fulani ti wọn n ṣejọba Naijiria ko ni itẹlọrun pupọ pẹlu awọn oyinbo ati awọn ti wọn yi wa ka ni Bẹnnẹ ati Cameroon, wọn mọ pe to ba da gbau, awọn ko le ba adugbo mejeeji yii lọ sibi kan. Ṣugbọn wọn mọ daadaa pe ti ohunkohun ba ṣelẹ ni Naijiria, bi wọn fẹsẹ rin wọ Nijee yii, ko sẹni to le da wọn duro. Idi niyi ti ọpọ awọn olowo wọn ṣe n lọọ da ileeṣẹ silẹ nibẹ, ti wọn n kọle sibẹ, bẹẹ Naijiria ni wọn n gbe.

Ki i ṣe pe ijọba Naijiria ni epo gidi kan to fẹẹ ra lati Nijee wa silẹ yii, kaka bẹẹ, wọn fẹẹ maa ko owo wa lọ sọhun-un lati fi tun orile-ede naa ṣe ni, wọn aa si ṣi ẹnubode wa fun wọn debii pe ara Nijee aa maa wọle si Naijiria, wọn aa maa jade bi wọn ti fẹ, ti ko sẹni kan to fẹẹ yẹ wọn wo. Yatọ si abuku to wa ninu eto tawọn Buhari lawọn n ṣe yii, eyi to buru gan-an fun gbogbo wa ju lọ ni eto aabo. Ọna yii lawọn Boko Haram n ba wọ Naijiria, ko si ibi meji ti wọn n ba wa, ọpọ awọn Boko Haram yii naa lo si jẹ ọmọ adugbo yii ni wọn. Nigba ti wọn ba de, ti wọn paayan titi, ijọba Naijiria aa ni wọn ti ronu piwada, awọn si ti dari ji wọn, ni wọn aa ba da wọn sinu iṣẹ ologun Naijiria, awọn ọmọ to jẹ ọmọ orilẹ-ede Nijee ni wọn: awọn ọmọ Fulani ti wọn ti di afẹmiṣofọ lọdọ wọn, ti ko si sẹni to le gba iṣẹ naa lọwọ wọn.

Bawọn Buhari funra wọn ti n kede pe eto ọrọ-aje ti bajẹ, atunṣe ẹ di ọwọ Ọlọrun, ti wọn n fi ojoojumọ jẹ gbese kun gbese, awọn kan yii naa ni wọn n run owo nla si Nijee, ti wọn ni awọn fẹẹ maa ra epo lati ọhun wa sile. Boya wọn fẹe ta Naijiria fun Nijee ni o, boya wọn si kuku fẹẹ ko awọn Fulani ati Hausa wọlu debii pe wọn aa gba Naijiria lọwọ awa to ku to ba ya, awọn nikan lo ye. Ṣugbon awa ti wọn n ṣe aburu yii fun naa la oo maa gbeja wọn, afi bii igba tawọn Fulani ti fi oogun kan mu Yoruba. Bi awọn oloṣelu iranu ti a ni nibi ba si foju kan Buhari ọhun, ẹrin wẹnnẹ bii tẹni ti wọn ṣepe fun ni, titi ti awọn yẹn aa fi fọgbọn le wọn jade. Tabi iru ibeere wo lawọn aṣaaju ẹgbe APC nilẹ Yoruba n beere lọwọ Buhari bi wọn ba ri i. Ṣe ohun to n ṣẹlẹ yii tẹ wọn lọrun ni! Mo si sọ to o! Mo pariwo fun Yoruba to! Ibi ta a ba ara wa de niyi o. Bẹẹ kinni ọhun ṣẹṣẹ bẹrẹ ni! Ẹru to n ba mi niyẹn.

2 thoughts on “Ẹru kan wa to n ba mi o

  1. E se Olootu, O di igbati Nijiria pa pin ki Emo lo loto, Ki Afe na lo loto ni a le gbadun. Oruko yi ki se awa ni a fun ara wa, Iba-gbeyi ko le sise titi Bila yio fi fon. Eranko Bilaa ko de ni fon Lialai. Awon Ole Agbagba Yoruba ti oun je ninu madaru yii ni won nfa ifa seyin fun wa. Idaduro Yoruba nikan ni o le se kini yii, bi a so Abebe soke N’gba Igba(200) ibi pelebe naa ni yio fi ma leele o. A de sese bere ni a o ti ri nkankan! A feran iro ni Orilede yii pupo ko de si aanfani ti yio se fun wa O.

    Nuga
    Chicago

Leave a Reply