Ẹsan awọn ẹgbọn mi ti wọn pa ni mo fẹẹ gba ti mo fi yinbọn pa ọmọ Mọdakẹkẹ- Ṣina

Florence Babaṣọla

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ti ṣafihan awọn afurasi mẹrin ti ọwọ tẹ lori wahala iṣekupani to waye lawọn abule kan niluu Mọdakẹkẹ laipẹ yii.

A oo ranti pe eeyan meje lo ku iku airotẹlẹ laarin oṣu karun-un si oju kẹjọ, ọdun yii, lagbegbe abule kan ti wọn n pe ni Alapata, awọn eeyan ilu Mọdakẹkẹ ati Ifẹ ni wọn si n da’ko nibẹ.

Diẹ lo ku ki iṣẹlẹ yii da ogun abẹle miiran silẹ laarin ilu Mọdakẹkẹ ati Ifẹ, ṣe lawọn ọdọ ilu mejeeji n naka aleebu sira wọn lori iṣẹlẹ naa, kia ni Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, atijọba ipinlẹ Ọṣun si n pariwo pe ki awọn araalu mejeeji ṣe ṣuuru nitori aṣiri awọn amookunṣika naa yoo tu.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Kọmiṣanna Ọlọkọde ṣafihan awọn mẹrin ti ọwọ ti tẹ lori iṣẹlẹ naa, to si sọ pe iṣẹ n lọ lọwọ lati mu awọn yooku. Awọn afurasi naa ni Akingbala Ọlakunle, Owoniyi Ṣẹgun, Daramọla Muideen ati Ṣina Adeyẹmi.

Nigba ti Ṣina n ba ALAROYE sọrọ, o ṣalaye pe ọmọ bibi agbegbe Okerewe, niluu Ileefẹ, loun, ati pe iṣẹ agbẹ loun yan laayo.

O ni ọjọ ti pẹ ti wahala abẹnu ti maa n waye laarin awọn eeyan ilu mejeeji labule naa, ati pe ẹgbọn oun ọkunrin mẹta ati obinrin kan ni wọn ti padanu ẹmi wọn sinu iṣẹlẹ naa latẹyinwa.

Ṣina sọ siwaju pe nigba ti awọn eeyan ilu Mọdakẹkẹ tun de lọjọ naa ni inu bi oun pẹlu iku awọn ẹgbọn oun, idi si niyẹn toun fi gbe ibọn sakabula, ti oun si yin in soke, lai mọ pe yoo ba ẹni to ba lọjọ naa, ti iyẹn si ku loju-ẹsẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ti waa ṣeleri pe ni kete ti awọn ba ti pari iwadii lori awọn afurasi naa ni wọn yoo foju bale-ẹjọ lati sọ ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ iṣekupani naa.

Leave a Reply