Ẹsọ Amọtẹkun ti ri mẹsan-an gba pada ninu awọn arinrin-ajo ti wọn ji gbe l’Akoko  

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Mẹsan-an ninu awọn arinrin-ajo mejila tawọn agbebọn kan ji gbe lagbegbe Ifira Akoko laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lawọn ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ ti ri gba pada lẹyin wakati diẹ ti wọn ko sọwọ awọn ajinigbe.

Abuja to jẹ olu-ilu orilẹ-ede yii la gbọ pe awọn arinrin-ajo naa ti n bọ kawọn janduku ọhun too da wọn lọna laarin oju ọna Ifira Akoko si Idoani.

Nigba to n fidi bi wọn ṣe ri awọn eeyan naa gba pada mulẹ fawọn oniroyin, oludari ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ naa, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni lọgan tawọn eeyan agbegbe naa pe awọn, ti wọn si fi ohun to ṣẹlẹ ọhun to awọn leti lawọn ti mori le agbegbe naa.

O ni lẹyin ọpọlọpọ akitiyan lawọn too ri bii awọn mẹsan-an gba pada lọwọ awọn onisẹẹbi ọhun nigba tawọn ẹsọ Amọtẹkun mi-in si tun wa lẹnu iṣẹ lọwọ lati ri i daju pe awọn arinrin-ajo to ku nikaawọ awọn ajinigbe ọhun gba ominira.

Bakan naa lo ni awọn funra awọn lawọn gbe ọkọ bọọsi elero mejidinlogun ti wọn wa ninu rẹ ati dẹrẹba mọto lọ si ọfiisi awọn ọlọpaa ni kete tiṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

Leave a Reply