Ẹsun ikowojẹ pẹlu ole jija: Olori awọn EFCC wọ gau!

*Bẹẹ ki i ṣe pe Magu n lọ sewọn ree

*Wọn fẹẹ fọrọ ẹ koba Tinubu pẹlu Ọṣinbajo o

Ademọla Adejare

Ọjọ Ẹti lọjọ naa bọ si, ọjo Jimọ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹfa, to kọja yii naa ni. Lọjọ yii lawọn amoye ti mọ pe omi ti gbẹ lẹyin ẹja fun olori ileeṣẹ amunimadaa ti wọn n pe ni EFCC, Ọgbẹni Ibrahim Magu. Ọjọ yii ni Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami, kọwe si Aarẹ Muhammadu Buhari, ọkunrin naa ko si fi ọrọ si abẹ ahọn sọ, o ni ki Buhari yọ Magu danu nipo olori EFCC, ko si fi ẹlomi-in si i. E e wa ti jẹ, e e ti ṣe? Malami ni Magu ko yẹ ni ipo naa nitori oun paapaa n ṣe owo ilu baṣubaṣu, awọn owo n sọnu mọ ọn lọwọ, gbogbo owo to si sọ pe oun n gba lọwọ awọn ti EFCC ba mu, ki i ṣe gbogbo ẹ lo n ko jiṣẹ, awọn dukia to si ni oun n ta lorukọ ijọba paapaa, oun nikan lo mọ awọn to n ta a fun, ko sẹlomi-in to tun mọ ohun ti Magu n ṣe. Malami ni ki ọrọ ma waa di pe ijọba Buhari fi ẹru ti wọn gba lọwọ ole kan ṣọ ole mi-in, ki wọn tete le Magu jinna, ko too ba wọn lorukọ jẹ, ko si too sọ ijọba yi lẹnu.

Awo lo ye, ko le ye awọn ọgbẹri, bi ọro naa ti ri niyẹn. Awọn awo mọ pe nnkan ti ṣe, nitori wọn mọ pe Magu ki i ṣe ẹni ti minisita kan n deede sọrọ si bẹẹ, oku ajanaku leeyan n yọ gbongbo si ni, ko si ẹnikan to jẹ yọ agada niwaju erin. Magu ti gbogbo minisita n bẹru, ti gbogbo awọn aṣofin n bẹru, ti gbogbo awọn ọga rẹ nileeṣẹ ọlọpaa bẹru de gongo, ti awọn olori ologun ko si jẹ pe tirẹ bawo, ṣe oun ni minisita kan yoo waa dide laaarọ ọjọ kan, ti yoo ni ki Buhari le Magu lọ! Awọn ọlọgbọn yii mọ pe nnkan ti bajẹ nile ijọba Aso Rock ni. Ko si sohun to fa eyi ju iku Abba Kyari to ku ni … lọ. Bi Kyari ba wa laye ni, iru ẹgbin ati iwọsi yii ko ni i ta le Magu. Loootọ Malami yii ni ọga Magu, nitori abẹ ileeṣẹ rẹ ni awọn EFCC wa, ṣugbọn Magu ko gba pe oun ni ọga miiran to ju Kyari lọ, nigba to si jẹ Kyari ni olori afọbajẹ Aso Rock, ẹni yoowu to ba duro ti lẹyin, bii pe Oluwa lo duro sẹyin onitọhun ni.

Agbara Kyari yii ni Magu fi n ṣe ohun gbogbo. Nitori bo tilẹ jẹ pe lẹẹmejeeji ti Aarẹ Buhari fi orukọ rẹ ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin pe ki wọn ba oun fọwọ si i gẹgẹ bii alaga EFCC, ti awọn yẹn kọ orukọ rẹ pe awọn o le fọwọ si i nitori ileeṣẹ DSS ti kọwe sawọn pe ọwọ Magu funra rẹ ko mọ, sibẹ, ọdun karun-un ree ti ọkunrin naa ti n ṣe adele alaga EFCC, ti ko si ṣenikan to to lati le e. Ohun to tilẹ foju awọn aṣofin ti ko gba orukọ rẹ wọle ri ko kere, nitori nigba ti EFCC ki Bukọla Saraki ti i ṣe olori wọn mọlẹ, igbẹ gbuuru ti idi ọkunrin naa jade. Bẹẹ naa ni wọn ṣe fun igbakeji rẹ, Ike Ekeremadu, ti wọn le e karakara nitori owo ti wọn lo ko jẹ. Ọrọ naa lo fa a to jẹ laarin ọdun mẹrin ti Saraki fi ṣe olori ile-igbimọ aṣofin agba, ọta gidi ni ile-igbimọ aṣofin naa ati awọn ọmọọṣẹ Buhari gbogbo.

Ohun to foju awọn olori awọn aṣofin yii ri mu ki gbogbo eeyan tubọ bẹru rẹ, ibẹru naa si tubọ pọ nigba ti wọn mu Olori awọn ologun ọtẹlẹmuyẹ NIA, Ayọdele Ọkẹ, ti wọn ni wọn ka owo nla mọ ọn lọwọ, ti wọn si tori rẹ yọ tọhun niṣẹ lẹsẹkẹsẹ. Nitori eyi, ati olori ṣọja ati olori ọlọpaa, ko sẹni ti ko bẹru Magu, wọn ṣaa ti mọ pe ọmọ Kyari ni. Ko si ẹnikan to lagbara ti ọkunrin naa ko le fi wọlẹ, yoo dẹ awọn ọmọ ogun rẹ si i ni. Awọn ọlọpaa onibọn ti oun naa si n lo ni EFCC, ko sẹni ti wọn ko le doju ibọn wọn kọ. Agbara Magu pọ debii pe igba kan wa ti awọn ọta Aishat Buhari ninu ijọba yii fẹẹ doju rẹ kọ obinrin naa, ki wọn too kilọ fun un ko ma jẹ ki wọn fi ori oun fọ agbọn. Pẹlu atilẹyin Kyari yii, Magu mọ pe ko sẹni ti yoo yọ oun niṣẹ yii titi ti Buhari yoo fi lọ, agaga nigba ti ọkunrin Wolii kan, Emmanuel Omale, tun waa riran si i pe bi araye fẹ, bi araye kọ, Buhari yoo tun oun Magu yan bii olori EFCC.

Ṣugbọn lojiji ni Kyari ku lai dagbere fẹnikan, nibi ti nnkan si ti bẹrẹ si i daru fun Magu niyẹn. Bo ti ku tan ni awọn eeyan bẹrẹ si i beere pe ki lọkunrin naa n ṣe nipo olori EFCC nigba tawọn aṣofin ko fọwọ si i, latigba naa ni awọn ọta rẹ si ti bẹrẹ si i gbara jọ. Malami to jẹ ọga rẹ ti ko sọrọ tẹlẹ bẹrẹ si i tu faili Magu wo, ko si pẹ rara ti wọn fi kan awọn aṣemaṣe gbogbo to ṣe. Lẹyin ti Malami kọ lẹta si Buhari ni wọn ti gbe igbimọ kan dide lati wadii Magu, Ayọ Salami, adajọ agba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to ti fẹyinti ni wọn si fi ṣe alaga. ALAROYE gbọ pe gbogbo bi wọn ti n ranṣẹ si Magu pe ko wa ni ko da wọn lohun, to fi wọn gun lagidi pe ko si ohun ti wọn yoo ṣe, bii aye Kyari lo pe e, to jẹ ohun to ba ṣe, aṣegbe ni. Nigba ti ko wa yii ni Malami ri wọn funra ẹ nileeṣẹ Aarẹ, ni wọn ba ni ki awọn ọlọpaa amunifunwaabajẹ lọọ gbe e wa.

Bo ti fẹẹ kuro ni ọọfiisi EFCC atijọ ni Wuse, ilu Abuja, nibẹ, ni wọn dabuu ẹ, ni wọn ba ni yoo ba awọn de Aso Rock gangan. N lo ba bẹrẹ si i sọ pe ki wọn maa lọ, oun yoo ba wọn, ṣugbọn awọn yẹn ta ku pe afi ko niṣo, nigba ti ọrọ si fẹẹ di a-n-yọbọn-sira-ẹni pẹlu awọn ọlọpaa moba to wa lẹyin Magu, n lọkunrin olori EFCC naa ba tẹle wọn. Bo ti de Aso Rock ni wọn tilẹkun mọ ọn, lati ọjọ naa, ko si ti i jade, nitori ibẹ lo ba lọ sitimọle ọlọpaa, to si tun pada waa kawọ sẹyin rojọ niwaju awọn igbimọ yii. Lati ọjọ to ti waa wa nibẹ ni aṣiri oriṣiiriṣii ti wa n tu sita. Ojoojumọ ni wọn n ka oriṣiiriṣii ile mọ ọn lọrun, awọn ile ti wọn lo wa ni Dubai ti Pasitọ Omale to rina si i lọjọsi ba a ra sibẹ pẹlu idaji biliọnu owo Naira, ati owo rẹpẹtẹ to ko fun lọọya Eko kan, miliọnu mejidinlọgbọn lẹẹkan naa.

Ọkunrin kan wa to ni Biroo-de-senji (Burreau de change), nibi ti wọn ti n ṣẹ owo dọla fun wọn, orukọ ọkunrin yii ni Ahmed Shanono, akaunti toun nikan si ni ni oriṣiiriṣii banki jẹ mejidinlọgọjọ (158), ajọṣe ti wọn lo wa laarin oun ati Magu bi ọrọ ba di ti owo dọla ko kere rara.

Diẹ lo ku ki awọn ti wọn ko ridii okodoro ọrọ fi ọrọ naa ko ba Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu, nigba ti wọn n sọ kiri pe owo kan ti wọn fi mọto agboworin gbe wa sile rẹ lọjọ ti ibo ku ọla, Magu lo fowo naa ranṣẹ si i. Eyi da wahala silẹ, ti awọn kan si ṣe iwọde nitori ẹ, pe afi ki awọn ọlọpaa mu Tinubu naa. Bẹẹ ni wọn tun ni Magu sọ niwaju igbimọ pe oun ko biliọnu mẹrin Naira fun Igbakeji Aarẹ Yẹmi Ọsinbajo. Ṣugbọn Magu funra rẹ ti sọ pe oun ko fun Tinubu lowo, bẹẹ ni oun ko si kowo kankan fun Ọṣinbajo, pe wọn kan fẹẹ fi ọrọ naa ko ba awọn mejeeji yii ni, oun kọ loun darukọ wọn. Ṣugbọn ti awọn ẹsun to ku, ko si ọṣẹ kan ti Magu ri fi wẹ mọ, wọn ti pa korobojo okun si i lọrun, yoo ṣoro gan-an ko too ribi yọ. Ohun to jẹ ki Aarẹ Buhari fọwọ si i ki wọn ṣi da a duro lẹnu iṣẹ naa ree, ki wọn ma jẹ ko pada si ileeṣẹ EFCC yii mọ, ti wọn si fi ọkan ninu awọn ọga nibẹ, Mohammed Umar, sibẹ pe ko maa ṣe adele alaga.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Magu ko ti i tan rara, nitori lojoojumọ lẹrii ṣi n jade si i, eyi naa ni wọn ko si ṣe fi i silẹ nitimọle, bo tilẹ jẹ pe o ti kọwe si ọga agba awọn ọlọpaa pe ko jẹ ki wọn gba beeli oun. Awọn ti wọn n ṣewadii ni kinni naa ko le ṣee ṣe bẹẹ, afi ti awọn ba pari iwadii naa tan, ki ọrọ ma si di pe awọn ọlọpaa EFCC ti wọn n pe ni ‘Awọn ọmọ Magu’ nibẹ da oju ọrọ ru, ileeṣẹ ọlọpaa ti fọn gbogbo wọn ka lẹsẹkẹsẹ, wọn gbe wọn kuro ni EFCC, wọn si fọn wọn si ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri. Eyi ni pe Magu ati eti rẹ nikan lo ku bayii, bi wọn ba si fi ẹsẹ awọn ọrọ naa mulẹ tan, afaimọ ki ọkunrin munimuni naa ma dero ẹwọn, nitori ohun ti tonile-talejo Abuja n sọ bayii ni pe Magu ti wọ gau, ko sọna ti yoo gba yọ.

 

Leave a Reply