Ẹsun ikowojẹ:Ile-ẹjọ fun Okorocha ni beeli

Jọkẹ Amọri
Miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ati oniduuro kan ni ile-ẹjọ giga to fikalẹ siluu Abuja ni ki gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, to tun jẹ sẹnetọ nileegbimọ aṣofin agba lọwọlọwọ, Rochas Okorocha, san gẹgẹ bii owo lati gba beeli rẹ lori ẹsun ikowojẹ to to biliọnu mẹta din diẹ (2,9b), ti wọn fi kan an.
Adajọ ile-ẹjọ giga naa, Onidaajọ Inyang Ekwo, lodi si awijare ajọ to n ri si ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati iwa ajẹbanu, EFCC lati ma ṣe fun ọkunrin naa ni beeli.
Bẹẹ lo paṣẹ pe ki Okorocha wa oniduuro kan ti yoo duro fun un pẹlu iye owo yii, to si gbọdọ jẹ ẹni to n gbe niluu Abuja. Bakan naa lo tun gbọdọ ni dukia to to iye owo beeli yii ni agbegbe kootu ọhun. Adajọ tun paṣẹ fun akọwe kootu lati ṣayẹwo dukia naa ni ibamu pẹlu aṣẹ ile-ẹjọ.
Laara awọn ofin ti adajọ fi de gomina naa ni pe ko gbọdọ rin irinajo kuro ni orileede yii lai jẹ pe ile-ẹjọ fọwọ si i, bẹẹ lo paṣẹ pe ki ile-ẹjọ gba iwe irinna rẹ silẹ.
Yatọ si eyi, Adajo Ekwo paṣẹ pe ki wọn kọwe si ileeṣẹ aṣọbode pe iwe irinna Okorocha wa ni akata awọn, nidii eyi, wọn ko gbọdọ gba a laaye lati kuro ni orileede yii.

Leave a Reply