Eto aabo ṣi maa buru ju bayii lọ, ayafi… – Ọbasanjọ

Faith Adebọla

Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ, ti sọ pe eto aabo to mẹhẹ lasiko yii, eremọde lo ṣi maa jẹ lẹgbẹ ohun to wa niwaju, ayafi ti awọn adari orileede ba wa nnkan ṣe sọrọ awọn majeṣin to yẹ ki wọn wa nileewe, ṣugbọn ti wọn ko ri ileewe lọ, ti wọn ko si ri iwe ka.
Ọjọbọ, Tọsidee yii, l’Ọbasanjọ sọrọ akiyesi ọhun ninu ọgba ile ikoweesi rẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library, to wa lọna Oke-Mọsan, l’Abẹokuta.

Lasiko to n sọrọ nibi gbọngan ti wọn ti n da awọn ọdọ lẹkọọ fun idagbasoke wọn, ti wọn pe ni Youth Development Centre. Ọbasanjọ ni ọgọọrọ awọn ọdọ ati ọmọde ni wọn ti di ọwọ to dilẹ ti eṣu n waṣẹ fun lasiko yii, eyi si lewu gidi fun ọjọọla orileede wa.

“Ṣe a nilo babalawo kankan lati difa ka too le mọ pe bi awọn ọmọ bii miliọnu mẹrinla to yẹ ki wọn wa nileewe, ṣugbọn ti wọn o rileewe lọ lasiko yii, irinṣẹ niru awọn ọmọ bẹẹ maa di fawọn eeṣin-o-kọ’ku Boko Haram, to ba fi maa di ọdun mẹwaa si mẹẹẹdogun sasiko yii, iyẹn to ba tiẹ to bẹẹ paapaa.

Tori bẹẹ, ta a ba tiẹ koju awọn Boko Haram lasiko yii, ta a si bori wọn, aṣeyọri ti ko le wa pẹ titi ni, tori laarin ọdun diẹ si i, nnkan tun maa buru ju bo ṣe wa yii lọ, eto aabo maa tun gogo si i ni.

Ta a ba n sọrọ nipa eto aabo to mẹhẹ, ibo lo yẹ ka ti bẹrẹ. Ta a ba n sọrọ nipa airowona ati ipo mẹkunnu, ibo lo ti yẹ ka mu ọrọ sọ? Ori eto ẹkọ ni gbogbo ẹ da le.

Ẹnikan sọ pe ti gbogbo wa ba kawee, ta lo maa fẹẹ ṣ’ẹru ẹnikan, ṣugbọn mo fesi pe ti gbogbo wa ba kawe, ẹru to mọwe, ọmọọdọ to jafafa, dẹrẹba to gboye-jade la maa ni, bi kaluku si ṣe maa maa ṣiṣẹ ẹ maa sunwọn ju bawọn ti o le fidi igo kọ ‘o’ yii ṣe n ṣe e lọ.

Ṣugbọn ti a o ba tete wa nnkan pato ṣe sọrọ aikawe awọn majeṣin rẹpẹtẹ yii, iwa janduku wọn maa buru ju tawọn Boko Haram ati awọn agbebọn wọnyi lọ.”

Ọbasanjọ lo n ṣalaye ọrọ bẹẹ.

Leave a Reply