Eto Aabo: Amọtẹkun ti bẹrẹ si i ṣọ ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati le dena iru ifẹmiṣofo to waye ninu ṣọọṣi katoliiki kan niluu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, laipẹ yii, ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun ti pin awọn oṣiṣẹ wọn kaakiri ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi lati le pese aabo to peye fun ẹmi awọn olujọsin.
Atẹjade kan latọwọ Agbẹnusọ ajọ naa, Yusuf Idowu, ṣalaye pe ohun to ba ni lọkan jẹ ni iṣẹlẹ ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, niluu Ọwọ, nibi ti aimọye ẹmi ti ṣofo, ti ọpọ si fara pa.
O ni ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun ko figba kankan tura silẹ rara, nitori ẹni ti wọn ba fi joye awodi gbọdọ le gbe adiyẹ, idi niyẹn ti awọn fi pin ara awọn kaakiri ileejọsin lati le daabo bo awọn eeyan lọwọ ikọlu to ba fẹẹ wa.
O ni awọn ko ni i tura silẹ rara, oniruuru awọn igbesẹ lawọn si n gbe labẹnu lati ri i pe omi ko tẹyin wọ igbin ipinlẹ yii lẹnu. Idowu ni yatọ si pe awọn wa kaakiri ṣọọṣi ati mọṣalaasi, awọn kan tun n lọ kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Ọṣun lọsan-loru.
Erongba ati afojusun Amọtẹkun l’Ọṣun gẹgẹ bo ṣe sọ ni lati ri i pe ipinlẹ yii gbona mọ awọn ọdaran, ti ko si ni i si ibi kankan ti wọn le sa si. O waa fi gbogbo awọn araalu lọkan balẹ lati maa ba iṣẹ wọn lọ lai bẹru rara.
Bakan naa lo rọ awọn ojiṣẹ Ọlọrun; pasitọ, imaamu, aafaa, awọn oniṣẹṣe, awọn ori-ade ati gbogbo awọn olugbe ipinlẹ yii lati maa ba awọn eeyan wọn sọrọ loorekoore lori ewu to wa ninu didaabo bo ẹnikẹni ti wọn ba fura si bii ọdaran.

Leave a Reply