Eto aabo n buru si i nipinlẹ Katsina, ojoojumọ ni wọn n jiiyan gbe nibẹ

Jide Alabi

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ko jọ pe apa gomina ipinlẹ Katsina, Aminu  Bello Masari, ka eto aabo ipinlẹ naa mọ, nitori ojoojumọ lo ku ti wọn n ji awọn eeyan gbe nibẹ bayii.

Ohun tọrọ naa fi n jọ awọn eeyan loju ni pe ipinlẹ ti Aarẹ ilẹ wa to jẹ olori eto aabo ti wa gan-an ni eto aabo ilu ti mẹhẹ bẹẹ.

Laarin ọsẹ mẹta sira wọn ni awọn ajinigbe ya wọ ileewe meji ọtọọtọ nipinlẹ naa, ti wọn si ji awọn akẹkọọ ibẹ ko lọ.

Awọn to mọ bo ṣe n lọ sọ f’ALAROYE pe owo nla ni wọn san ki wọn too ri awọn ọmọ ọhun gba pada.

Awọn akẹkọọ ileewe giga kan to n jẹ Government Science Secondary School, niluu Kankara, nipinlẹ  Katsina, ti wọn le ni ọọdunrun ti wọn ṣẹṣẹ ri gba pada ni awọn araalu n sọ lọwọ ki ajalu mi-in too tun ja nipinlẹ kan naa pẹlu bi ariwo ṣe tun gba ilu kan laaarọ ọjọ Aiku, Sannde yii, pe awọn ajinigbe yii ti tun ji awọn akẹkọọ mẹrinlelọgọrin mi-in ko.

Ileewe Islamiyya ti wọn ti n kọ wọn ni keu to wa niluu Mahuta, nijọba ibilẹ Dandume, ni wọn lawọn ọmọ naa ti ṣetan nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, ti kaluku wọn si kọri sọna ile wọn.

Ohun ta a gbọ ni pe ibi tawọn majeṣin yii ti n kọwọọrin pada sile wọn lawọn agbebọn kan ti rẹbuu wọn, nitosi abule Unguwar Al-Kasim, wọn si gbe mẹrinlelọgọrin lọ ninu wọn, bẹẹ lawọn diẹ lara wọn raaye sa asala fẹmii wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina, Ọgbẹni Gambo Isah, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ajinigbe naa ti kọkọ ji awọn ọmọde mẹrin ati maaluu mejila kan gbe lati abule ti wọn ti n bọ, ki wọn too pade awọn akẹkọọ wọnyi lọna.

ALAROYE gbọ pe wọn ti ri awọn bii ọgọrin gba pada ninu awọn ọmọ ọhun, bo tilẹ jẹ pe oju bọrọ kọ la n gbọmọ lọwọ ekurọ lọrọ ohun, niṣe lawọn ajinigbe naa n yinbọ lu awọn agbofinro, tawọn naa si dana ya wọn pada, eeyan mẹrin lo fara gbọta ninu awọn ajinigbe ọhun, kawọn yoo ku to sa lọ.

O lawọn agbofinro atawọn fijilante agbegbe naa ti lepa awọn ajinigbe naa lọ.

Isah ni awọn ọtẹlẹmuyẹ atawọn fijilante ti bẹrẹ iwadii lakọtun, wọn ti n wọ awọn igbo to yi agbegbe naa ka lati dọdẹ awọn ajinigbe to le sapamọ sibẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ko ti i ju ọsẹ meji lọ bayii tiru iṣẹlẹ aburu yii waye nipinlẹ Katsina yii kan naa, to jẹ ilu abinibi olori orile-ede wa, Ọgagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, nibi ti awọn janduku kan ti ya wọn ileewe ijọba, Government Science Secondary School, ni Kankara, nipinlẹ Katsina, ti wọn si ji awọn akẹkọọ bii ọjilelọọọdunrun ati mẹrin (344) sa lọ.

Ọṣẹ to kọja ni wọn pada ko awọn ọmọ naa wale lati ipinlẹ Zamfara ti wọn ni wọn ti ri wọn.

Oriṣiiriṣii iriri lawọn ọmọ ọhun n sọ bayii nipa ohun ti oju wọn ri, bẹẹ ni wọn sọ pe irọ lawọn eeyan ọhun pa, wọn ki i ṣe Boko Haram, ati pe nigba ti awọn ri i bi awọn ẹṣọ agbofinro ọhun ṣe n rọjo ibọn lu awọn lati oju ofurufu lo jẹ kawọn pe wọn ni Boko Haram.

Ọkan ninu awọn ọmọ naa sọ pe pẹlu ibẹru-bojo lọkan ninu wọn fi ni ki oun sare ṣe fidio pe ti awọn ẹṣọ ọhun ko ba dawọ ibọn ti wọn n yin duro, pipa lawọn yoo pa gbogbo awọn danu.

Farouq Aminu ninu ọrọ tiẹ sọ pe, “Bi mo ṣe n sọrọ yii, ara mi ko ti i balẹ rara, mo nilo alaafia gidi, ọpọ maili lawọn ajinigbe yii fipa mu wa rin, bẹẹ ni wọn tun fiya jẹ awọn kan ninu wa ti irin wọn ko ya kanmọ-kanmọ bii tiwọn. Odunkun ni wọn fun wa jẹ ati ẹgẹ, bẹẹ ki i ṣe ojoojumọ la n jẹun, iya buruku ni wọn fi jẹ wa, bẹẹ lawọn mi-in ninu wa ri awọn eeso jẹ pẹlu.’’

Ọmọ yii fi kun un pe oun ko gbọ pe ẹnikẹni ku ninu awọn. O ni bi wọn ṣe tu awọn silẹ, wọn kọkọ ko awọn lọ si ibi kan nipinlẹ Zamfara, iyẹn Tsafe, ko too di pe wọn ko awọn wa si Katsina.

Abubakar Sodiq sọ ni tiẹ pe ni kete ti wọn ti ji awọn gbe ni wahala ọhun ti bẹrẹ, bi wọn ṣe n yinbọn soke ni wọn n kilọ fawọn pe awọn ko waa ṣere o, ẹni to ba fẹẹ ṣe bii akọni laarin awọn, iku ni o.

‘‘Igba to ba wu wọn ni wọn n fun wa lounjẹ, bẹẹ omi to dọti patapata ni wọn tun n fun wa mu pẹlu. Eyi gan-an lo ṣokunfa bi awọn kan ninu wa ṣe dubulẹ aisan, emi paapaa, ara mi ko ya rara, mo fẹẹ lọ sile.”

Yusuf Sulaiman ninu ọrọ tiẹ sọ pe eto aabo ti ko munadoko to nileewe awọn lo fa a ti awọn janduku ajinigbe ọhun ṣe raaye wọle, ti wọn si ji awọn gbe. Ọmọ yii ti sọ fawọn oniroyin pe ko daju pe oun yoo tun pada sileewe ọhun mọ, nitori ko si aabo gidi kan bayii nibẹ.

Yatọ si eyi, ọkan lara awọn ọmọ ti wọn tu silẹ yii to wa ninu fidio ti awọn to ji wọn gbe fi sita sọ pe niṣe ni wọn fipa mu oun ki oun sọ pe awọn Boko Haram ti Abubakar Shekau, gan-an lo ji awọn  gbe.

Eyi ati ohun mi-in loriṣiiriṣii lawọn ọmọ naa n sọ, paapaa nipa iriri wọn. Bi awọn kan ninu wọn ṣe n sọ pe ko daju pe awọn yoo pada sileewe ọhun mọ, bẹẹ lawọn mi-in paapaa n sọ pe ohun ti oju awọn ri ki i ṣe ohun to rọju rara.

Ṣugbọn lasiko ti Aarẹ gbalejo awọn ọmọ naa lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, o ba awọn akẹkọọ naa sọrọ ni Banquet Hall, to wa nile ijọba, nipinlẹ Katsina, o si gba awọn ọmọ naa niyanju pe ki awọn akẹkọọ yii ma jẹ ki iṣẹlẹ to ṣẹlẹ naa, ati iriri ti wọn ni lọwọ awọn janduku ọhun da omi tutu si wọn lọkan, ki wọn kọju mọ iwe wọn daadaa.

Buhari to ṣalaye awọn ohun ti oun naa dojukọ laye sọ pe oun ko jẹ ki awọn idojukọ yii di oun lọọ lati tẹsiwaju.

Aarẹ ni, ‘‘Mo ki ẹyin akẹkọọ yii ku oriire, ẹ ma jẹ ki iriri yin lọdọ awọn janduku yii da omi tutu si yin lọkan, ẹ gbagbe gbogbo ohun to ti ṣẹlẹ, kẹ ẹ si kọju mọ iwe yin.

‘‘Ijọba yoo tẹsiwaju lati pese eto aabo to yẹ kaakiri awọn ileewe lorileede yii.’’

Iṣẹlẹ yii lo mu ki ẹgbẹ oṣelu APC bẹrẹ si i bẹ awọn araalu pe ki wọn ma ṣe kọyin si ijọba awọn, ki wọn dariji awọn.

Ẹgbẹ yii rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ Naijiria, wọn ni: “Ẹ fori ji ẹgbẹ wa, ẹ ma kẹyin si iṣejọba wa, iṣẹlẹ yii ko tun ni i waye mọ”

Alaga igbimọ afun-n-ṣọ to n tukọ ẹgbẹ naa bayii, Mai Mala Buni, to tun jẹ gomina ipinlẹ Yobe, lo sọrọ naa lorukọ ẹgbẹ APC, ninu atẹjade kan to fi sode lọjọ Abamẹta, Satide, tọ kọja  yii, l’Abuja.

Atẹjade naa sọ pe APC ki awọn ọmọleewe ojilelọọọdunrun ati mẹrin ti wọn ṣẹṣẹ gba itusilẹ naa atawọn obi, mọlẹbi ati ọrẹ wọn ku oriire.

O ni ibanujẹ nla niṣẹlẹ naa jẹ fun ẹgbẹ awọn, tori niṣe ni ọrọ ọhun mu ki isapa awọn lori ọrọ aabo da bii ẹni pe awọn ko ṣe nnkan kan. O lawọn yoo tubọ ṣiṣẹ kara lati dẹkun iwa janduku ati ijinigbe, lati mu ki eto aabo sunwọn si i jake-jado orile-ede yii.

O ni lorukọ ẹgbẹ APC, oun mu un da awọn ọmọ orile-ede yii loju pe iru iṣẹlẹ yii ko tun ni i waye mọ, gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un.

Ṣugbọn ko ti i pe wakati mẹrinlelogun to sọrọ naa ti wọn tun fi ji awọn akẹkọọ mi-in gbe.

Leave a Reply