Adewale Adeoye
Olori orile-ede yii, Aare Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe lara ohun to jẹ oun logun ju lọ bayii ni bi gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii ṣe maa janfaani eto ẹkọ-ọfẹ to ye kooro lakooko iṣakooso oun.
Aarẹ Tinubu ni ki i ṣe dandan rara pe awọn ọmọ olowo nikan ni wọn gbọdọ kawe nilẹ wa, ọ ni awọn ọmọ talaka paapaa gbọdọ kawe dojú amin debi ti wọn ba fẹẹ de.
O sọrọ yii di mímọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lakooko to n ba awọn aṣoju ẹgbẹ akẹkọọ ‘National Association Of Nigerian Student’ (NAN), sọrọ niluu Abuja.
Aarẹ Tinubu ni ìṣẹ́ tabi ailowo lọwọ awọn obi ọmọ ko gbọdọ di eto ẹkọ ọmọ wọn lọwọ rara, nitori pe eto ẹkọ wa lara ojulowo irinṣẹ ti wọn fí le bori ìṣẹ́ lawujo wa.
O ni, ‘‘Awọn ọmọ talaka tawọn obi wọn ko ja mọ nnkan kan laarin ilu gbọdọ le kawe doju amin ba a ba gbagbọ pe eto ẹkọ iwe le yanju iṣẹ laarin ilu, a gbọdọ na owo lori eto ọhun gidi ni. Bi ọkan lara awọn ẹbi kan ba ti yan, to yanjú, onitọhun le ran awọn yòókù rẹ lọwọ daadaa láti dìde soke.
Olori orileede wa naa tun fi da awọn aṣoju ẹgbẹ NAN ti wọn waa ki i lọfiisi rẹ niluu Abuja loju pe, oun yoo ri si ẹdun ọkan wọn, bakan naa lo gba wọn niyanju pe ki gbogbo wọn pata fimọ ṣọkan nigba gbogbo lori ohun ti wọn ba n beere lọwọ ijọba.