Eto idibo ṣii n lọ lọwọ ni ipinlẹ Edo

Aderounmu Kazeem

Eto idibo sipo gomina ti wọn n di loni-in yii ni ipinlẹ Edo ṣii n lọ lọwo o, ẹgbẹ oṣelu mẹrinla lo si n kopa ninu idibo ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe mẹrinla lawọn ẹgbẹ oṣelu to jade, sibẹ ẹgbẹ oṣelu meji, APC ati PDP ni wọn lẹnu ju ninu ọrọ to wa nilẹ yii, gbogbo eeyan lo si mọ pe laarin Gomina Godwin Obaseki ati Pasitọ Ize Iyamu ni wọn gbọdọ wa ipo naa si.

Awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ti duro wamu, awọn ẹṣo agbofinro naa ti wa kaakiri pẹlu, ti awọn oludibo paapaa ti bẹrẹ si tu jade, ti ayẹwo orukọ si ti bẹrẹ ni perẹu. Koda lawọn agbegbe kan, idibo ti n waye daadaa.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, wọọrọwọ ni gbogbo eto ọhun n lọ, bẹẹ ni gbogbo titi, paapaa igboro ilu Benin naa da, ti ko si wọlukọlu ọkọ rara.

Wọọdu mẹtalelaadọwa (193) lo wa nipinlẹ Edo pẹlu ijọba ibilẹ mejidinlogun. Ohun to si foju han bayii ni pe, pẹlu alaafia ni kaluku fi n ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe, ti awọn ẹṣọ naa si n woye bi ohun gbogbo ṣe n lọ.

Loni-in ni o, nibi ti awọn eeyan Edo fẹẹ lọ gan-an ati ẹni ti wọn fẹẹ nipo gomina, ko ni i pẹ ti iroyin ọhun yoo maa jade.

 

Leave a Reply