Eto idibo ku si dẹdẹ, oludije sipo aṣoju-ṣofin ku lojiji

Monisọla Saka

Riro ni teniya, ṣiṣe ni ti Ọlọrun Ọba ni ọrọ oludije funpo ileegbimọ aṣoju-ṣofin, to n ṣoju ẹkun Birnin Kebbi, Bunza, ati Kalgo lẹgbẹ PDP, Abba Bello Muhammad, to ti n mura, to si n polongo ibo ni imurasilẹ fun eto idibo ti yoo waye ninu oṣu Keji, ọdun yii, ṣugbọn to pada ku lojiji lẹyin aisan ranpẹ.

Oloogbe Abba ni akọbi lọkunrin fun alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nigba kan ri, Dokita Bello Haliru.

Oun lo gbegba oroke ninu ibo abẹle ẹgbẹ wọn lọdun to kọja, lẹyin to fẹyin ẹni to wa nibẹ tẹlẹ, Bello Relisco janlẹ.

Ninu atẹjade kan ti igbimọ olupolongo ibo ẹgbẹ naa, ti Abubakar Usman ṣoju fun, ni wọn ti ṣedaro ọkan pataki ninu ọmọ ẹgbẹ wọn ti wọn lo ku lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lẹyin aarẹ diẹ.

Awọn igbimọ yii ni, iroyin iku oloogbe ba awọn lojiji, bẹẹ ni ọkan awọn si gbọgbẹ, pẹlu bi iku ṣe mu un lọ ni o ku oṣu kan ati ọjọ diẹ ki eto idibo waye, gẹgẹ bi wọn ṣe ti gbe e jade pe ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ni wọn yoo dibo aarẹ, igbakeji aarẹ, ati ti ile igbimọ aṣofin mejeeji.

Nitori idi eyi ni wọn ṣe paṣẹ pe ki wọn da gbogbo eto ipolongo ibo atawọn nnkan mi-in lẹgbẹ wọn duro titi digba ti wọn ba tun maa sọrọ lori ẹ.

Ilu Abuja la gbọ pe wọn sin oku rẹ si lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

 

Leave a Reply