Eto idibo ọdun 2023 lo maa sọ boya Naijiria ṣi maa wa, tabi yoo fọ si wẹwẹ-Jega

Faith Adebọla

Ọjọgbọn Attahiru Jega ti i ṣe alaga tẹlẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), ti ṣekilọ pe diẹ lo ku ki gbogbo nnkan dẹnu kọlẹ patapata lorileede yii, bi ko ba si si ayipada rere to gunmọ, niṣeju gbogbo wa ni Naijiria yoo fi fẹyin balẹ, ti yoo si dohun itan.

O ni omi to fẹẹ gbẹ lẹyin ẹja orileede yii ko ṣadeede waye, awọn aṣaaju ti wọn n tukọ iṣakoso rẹ ni wọn ya alaibikitia ati ọdaju, o lawọn ni wọn mọ-ọn-mọ diju mọri lati fẹyin Naijiria balẹ yakata, bẹẹ gbogbo wọn o ju bintin lọ, wọn o pọ rara.

Nibi apero akanṣe kan to da lori eto oṣelu orileede wa, eyi ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lapapọ, NLC, ṣagbatẹru rẹ l’Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii, ni Jẹga ti sọrọ ikilọ ọhun gẹgẹ bii olubanisọrọ pataki.

Jẹga ni eto idibo gbogbogbo to n bọ lọdun 2023 yii lo maa sọ boya Naijiria yoo ṣi maa jẹ Naijiria niṣo tabi ki orileede naa fọ si wẹwẹ.

“Ipo to ṣe ni laaanu gidi ni ọrọ-aje ati igbaye-gbadun awọn eeyan wa ni Naijiria lọwọ yii, labẹ ipo naa si lawọn oṣiṣẹ ati eyi to pọ ju lọ ninu ọmọ Naijiria n gbe ti wọn si n ṣiṣẹ.

“Awujọ awọn eeyan bintin kan ti wọn jẹ aṣaaju ati alẹnulọrọ nidii eto iṣakoso Naijiria, awọn to jẹ pe a o yan wọn, niṣe ni wọn yan ara wọn, ti wọn si sọ ara wọn daṣaaju, awọn ni wọn n ṣe nnkan baṣubaṣu nilẹ wa, gbogbo okun ajọṣe ati irẹpọ to so wa pọ bii orileede kan ni wọn yọ ọbẹ ti, ti wọn n rẹ danu, awọn ni wọn wa nidii ọrọ-aje to dori kodo, eto aabo to polukurumuṣu, ti wọn si n bẹgi dina ati goke agba orileede wa.

“Afi ta a ba gbe igbesẹ gidi lati doola ẹmi orileede yii. Ki iru igbesẹ bẹẹ si too le ṣiṣẹ, ko si yọri si rere, afi ki awọn oṣiṣẹ da si i, nipa kikopa to jọju ninu eto yiyan aṣoju rere, ki wọn si fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn eeyan ati ẹgbẹ to lero rere lọkan forileede yii, lati ri i pe awọn ojulowo ọmọ Naijiria atata lo bọ sipo oṣelu ati akoso.

“Loootọ ni Naijiria ṣi n mi, ṣugbọn wọn ti fẹẹ fẹyin ẹ balẹ, awọn aṣaaju alaibikita to n ṣakoso yii kan diju mọri lati fẹyin rẹ balẹ yakata ni, eto idibo gbogbogboo ọdun 2023 to n bọ yii lo maa yanju ẹ, boya Naijiria yoo ṣi wa lodidi abi o maa tuka.

“Pẹlu gbogbo eyi, ẹyin tẹ ẹ ba lẹmi itẹsiwaju, tẹ ẹ jẹ afẹnifẹre, ti ọrọ Naijiria si jẹ yin logun gbọdọ kora jọ, kẹ ẹ sapa lati ma ṣe jẹ ki orileede yii wo, ki ayipada le de, nipa iṣejọba rere, eto ọrọ-aje to nitumọ ati eto aabo to jiire. Agan lọrọ to delẹ yii o, ko ṣee da gbe, afi ka jọ gbe e.”

Leave a Reply