Eto isinku Bamidele Olumilua bẹrẹ, oku oloogbe kọja si Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, ti gba oku Gomina Ondo atijọ, Bamidele Olumilua, lọwọ Gomina Rotimi Akeredolu tipinlẹ Ondo pẹlu bi eto isinku baba naa ṣe bẹrẹ lonii.

Lọsan-an oni ni eto naa waye niluu Ikẹrẹ-Ekiti, nibi tawọn gomina mejeeji ti pade lati ṣayẹyẹ kekere ọhun.

Fun ọsẹ kan gbako ni isinku Olumilua yoo fi waye, ipinlẹ mejeeji ni yoo si ṣagbatẹru ayẹyẹ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko wa ọpọ eeyan nibẹ pẹlu ofin konilegbele to mulẹ nipinlẹ Ekiti.

Laarin ọdun 1992 si 1993 ni Olumilua fi jẹ gomina lasiko ti Ondo ati Ekiti wa papọ, iyẹn laye iṣejọba Ọgagun Ibrahim Babangida.

Ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa, ọdun yii, lo dagbere faye lẹni ọgọrin ọdun.

Leave a Reply