Eto ti n lọ lati sinku Ọba Saliu Adetunji, Olubadan ilẹ Ibadan, to waja

Jọkẹ Amọri

Bi gbogbo nnkan ba lọ bi wọn ṣe ṣeto rẹ, ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu kin-in-ni yii, ni wọn yoo si Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, to waja lẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un.

Aarọ ọjọ Aiku ni kabiyesi darapọ mọ awọn baba nla rẹ lẹyin aisan ranpẹ to ṣe e, ti wọn si gbe e lọ si ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun to wa niluu Ibadan, iyẹn University Teaching Hospital.

Ni nnkan bii aago mọkanla ku diẹ ni wọn gbe oku Ọba Saliu Adetunji pada si aafin to wa ni Popo Yemọja, nibi ti eto ti n lọ lọwọ lati sinku rẹ ni ilana Musulumi.

Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn eeyan to wa laafin to si tun jẹ akowe iroyin fun kabiyesi, Adeọla Ọlọkọ ṣe sọ, o ni ni nnkan bii aago kan oru ọjọ Aiku ni kabiyesi waja.

Ojọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun 2016 ni ọba naa gbọpa aṣẹ gẹgẹ bii Olubadan kọkanlelogoji.

Oun lo si rọpo Ọba Samuel Odulana Odugade.

Leave a Reply