Ẹwọn ọdun mejidinlọgọrun-un nile-ẹjọ ju iyaale ile to ja banki lole si n’Ibadan  

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ẹwọn ọdun mejidinlọgọrun-un (98) nile-ẹjọ sọ oṣiṣẹ banki kan, Ọrẹoluwa Adeṣakin si, ileefowopamọ lo ja lole owo nla.

Ọrẹoluwa ni ẹka ileefowopamọ First Bank to n ba ṣiṣẹ nigboro Ibadan fi si ẹka awọn onibaara wọn to ba fẹẹ fowo ranṣẹ silẹ okeere.

Ipo yii lo lo lati fi owo banki naa ranṣẹ sinu aṣunwọn ara ẹ lọdun 2013, tawọn ọga ẹ ko si mọ nnkan kan.

Ṣugbọn lọjọ ti wọn ṣe iṣiro bowo ṣe wọle ati bo ṣe jade nileeṣẹ wọn lọdun naa ni wọn ri i gbangba pe ìyáláje ti fẹẹ sọ ileefowopamọ naa soko gbese. Nigba naa ni wọn fi ọro ẹ to awọn EFCC, iyẹn ajọ to n gbogun ti jibiti owo ati iwa magomago leti.

Gẹgẹ bi agbẹjọro EFCC ẹkun Ibadan, Amofin Usman Murtala, ṣe fidi ẹ mulẹ ninu ẹsun mẹrinla ti wọn ka si i lẹsẹ niwaju adajọ, ẹẹmeji lolujẹjọ ja banki to n ba ṣiṣẹ lole owo nla nla.

Owo to fẹẹ to ọtalelọọọdunrun miliọnu Naira (N49,320,652.32 ) lo kọkọ taari sinu akanti ara rẹ ninu oṣu karun-un, ọdun 2013.

Lẹyin oṣu mẹfa, nigba ti ilẹ ta si i diẹ, to ri i pe ko sẹni to fura si ole ti oun kọkọ ja lọjọsi, lo kuku gbe owo ilẹ okeere to fi dọla meji din ni ẹgbẹrun lọna ọtalelọọọdunrun dọla ($368,203) ninu oṣu kẹfa, ọdun naa. Eyi si le ni miliọnu lọna ogoje Naira daadaa ba a ba gbe e si iṣiro owo ilẹ yii.

Ọdun 2014, iyẹn lọdun keji to huwa jibiti ọhun lajọ EFCC gbe e lọ si kootu fẹsun jija banki lole ati didọgbọn si akọsilẹ ileefowopamọ naa lati fi bo iwa ole rẹ mọlẹ.

Gbogbo ẹsun mẹrẹẹrinla ti wọn fi kan olujẹjọ yii lo tako, o loun ko jẹbi ọkankan ninu wọn pẹlu alaye.

Ṣugbọn gbogbo awijare rẹ ko ta leti Onidaajọ Muniru Ọlagunju ti i ṣe adajọ kootu naa, o ni gbogbo ẹri ti ajọ EFCC ko silẹ lati tako olujẹjọ ti fi han gbangba pe niṣe niya naa ja banki to gba a siṣẹ lole.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii nidaajọ waye, nigba ti Onidaajọ Ọlagunju sọ obinrin naa sẹwọn ọdun meje meje lori ọkọọkan awọn ẹsun naa. Apapọ ọdun meje lọna mẹrinla ni iba fi jẹ ọdun mejidinlọgọrun-un (98) ti iba lo lẹwọn, ṣugbọn adajọ ti gba a laye lati ṣe ẹwọn naa papọ lasiko kan naa. Eyi ni yoo si fun un lanfaani lati lo ọdun meje pere lahaamọ ọgba ẹwọn Agodi n’Ibadan.

 

Leave a Reply