Ẹwọn ọrinlelẹgbẹrun ọdun (1,800), ni wọn ju Abram to fipa ba obinrin mẹrindinlọgọta lo pọ si

Bo ba jẹ pe eeyan le ku ki wọn tun ji tọhun dide pe ko maa waa ṣẹwọn rẹ lọ ni, afaimọ ni wọn o ni i ṣe bẹẹ fun ọkunrin ọdaran ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ti wọn porukọ ẹ ni Abram Sello Mapunya yii, tori o daju pe ko si bi ẹmi rẹ ṣe le gun to, ko le pari ẹwọn ẹgbẹrun kan ati ọdun mejidinlaaadọrun-un tile-ẹjọ sọ ọ si, latari bo ṣe jẹbi ẹsun fifipa ba awọn obinrin mẹrindinlọgọta lo pọ.

Ọmọ bibi orileede South Africa ni Abram, ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Pretoria, lorileede naa lo gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ Ẹti, Furaidee yii, wọn ni laarin ọdun marun-un ni baale ile ọdaran yii fi ṣe awọn obinrin olobinrin baṣubaṣu, o si jẹbi ẹsun mọkanlelọgọrin (81) ninu ọgọrun kan le ọkan (101) ẹsun ti wọn kọkọ fi kan an.

Mọkanlelogoji (41) lara awọn ẹsun ọhun lo da lori ifipa ba ni lo pọ, nigba ti ẹsun ogoji yooku jẹ mọ ole jija, ṣiṣe akọlu sawọn ẹni ẹlẹni, fifọle, ati hihuwa to le da omi alaafia adugbo ru.

Adajọ to dajọ ẹwọn fọpa-wọn ọhun, Papi Mosopa, sọ pe ọmọ ọdun mẹrinla lọjọ ori ẹ kere ju ninu awọn ti jagunlabi yii fipa ṣe ‘kinni’ fun, ẹni ọdun marundinlọgọta lo dagba ju ninu wọn.

Wọn ni bo ṣe n lọ lati agbegbe kan si omi-in lo n huwakiwa ọhun, lara awọn ilu to gbe iṣe ẹ de ni Nellmapius, Mamelodi, Silverton, Olievenhoutbosch ati Atteridgeville.

Wọn lọkunrin naa ati ọrẹbinrin kan ni wọn jọ n gbe, ko fẹ ẹ bii iyawo o, ṣugbọn wọn lo lọmọ meji, ọmọkunrin to jẹ ọdun mẹjọ, atọmọbinrin ọdun mẹrin kan.

Adajọ naa ni lati ọdun 2014 ni ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ ti fihan pe Abram ti gbegba ṣina ati gbewiri ẹ, ko si jawọ, bẹẹ ni ko ronupiwada titi tọwọ awọn agbofinro fi tẹ ẹ loṣu kẹta, ọdun 2019, ti wọn si ti foju ẹ bale-ẹjọ.

Sibẹ, lasiko igbẹjọ, adajọ ni oun o gbooorun ironupiwada kankan lara ẹ, wọn niṣe lo n rẹrin-in musẹ ni kootu, ko tiẹ huwa bii ẹni to mọ itumọ aburu to ṣe rara.

Latari eyi, adajọ ni iru ẹ kọ lo yẹ ko tun maa gbe laarin awọn eeyan gidi, ko lọọ maa fi aṣọ penpe roko ọba ni, ẹwọn si ni ko ti lo iyooku igbesi aye rẹ, koda to ba tun aye wa paapaa.

Leave a Reply