Ẹwọn n run nimu Ṣeyi o, aṣẹwo lo fipa ba lo pọ n’Ilupeju-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa ni Ado-Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn fi ọmọdekunrin kan, Ajibowu Seyi, si ọgba ẹwọn to wa niluu naa.

Ṣeyi, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to tun  jẹ gbajugbaja ọlokada niluu naa ni wọn gbe wa sile-ẹjọ lori ẹsun kan ṣoṣo pe o fipa ba obinrin aṣẹwo kan lo pọ ni ogunjọ, oṣun kọkanla, ọdun yii, ni adugbo Ararọmi.

Lasiko igbẹjọ naa, Agbefọba ile-ẹjọ yii, Insipẹkitọ Akinwale Oriyọmi, kọkọ tọrọ aaye lọwọ kootu naa pe ki wọn fi ọdaran naa pamọ si ọgba ẹwọn fun igba diẹ ki oun le raaye gbe faili ẹjọ naa ranṣẹ si ileeṣẹ ijọba fun imọran.
Ninu ẹjọ ti obinrin aṣẹwo naa ro nile-ẹjọ, o sọ pe loootọ loun gba lati sun ti Ṣeyi lalẹ ọjọ kan pere ni ileetura Brothel, to wa ni Ilupeju-Ekiti, pẹlu adehun pe yoo san ẹgbẹrun marun-un Naira fun oun.

O ni o ya oun lẹnu nigba ti oun ṣadeede ri Ṣeyi ati ọrẹ rẹ kan ti oun ko mọ orukọ rẹ, ti awọn mejeeji si fipa ba oun lo pọ.
Aṣewo yii ni wọn gba owo ti oun ko dani to to ẹgbẹrun marun-un Naira, bakan naa ni wọn tun gba ẹrọ ilewọ oun, ti wọn si ja oun sihooho.
Eyi lo ni o mu ki oun lọọ fọrọ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa, ti wọn si mu Ṣeyi, ṣugbọn ti ekeji rẹ sa lọ

Bakan naa lobinrin yii ni oun ti fọrọ naa to ileeṣẹ ijọba to n gbogun ti fifi ipa ba obinrin lo pọ leti.

Ile-ẹjọ ti sun igbẹjọ ọhun si ọjọ kẹtala, oṣu kejila, ọdun 2021.

Leave a Reply