Ẹwọn n run nimu Atofarati, ile onile lo lọọ fọ n’Ilawẹ-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

To ba ṣe pe loootọ ni ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Bọla Atofarati, fọ ile onile niluu Ilawẹ-Ekiti, to si tun ja ẹni ẹlẹni lole, a jẹ pe orukọ ko ro afurasi naa rara.

Atofarati lawọn ọlọpaa sọ pe ọwọ tẹ lori iṣẹlẹ kan to waye ni Aaye Quarters, n’Ilawẹ-Ekiti, lọjọ kẹta, oṣu to kọja, laarin aago mẹjọ aabọ si mẹrin irọle, eyi ti ẹni tọrọ kan fi to awọn leti.

Agbẹnusọ ọlọpaa, Bankọle Ọlasunkanmi, sọ fun kootu Majisteeri-agba ilu Ado-Ekiti to wọ olujẹjọ naa lọ pe ile ọkunrin kan to n jẹ Adekayero Adeṣuyi ni Atofarati fọ lọjọ iṣẹlẹ ọhun, awọn nnkan to si ji le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọtalenigba naira (N263,000).

O ṣalaye pe owo to jẹ ẹgbẹrun lọna igba (N200,000), idaji apo irẹsi, redio igbalode kan ati foonu Tecno L9 lọkunrin naa gbe kọwọ too tẹ ẹ, eyi lo jẹ kawọn fẹsun ile fifọ ati ole jija kan an nilana ofin to de iwa ọdaran l’Ekiti.

O rọ kootu naa lati sun ẹjọ siwaju, bẹẹ lo ni awọn ẹlẹrii wa nilẹ ti yoo tan imọlẹ sọrọ naa ko le rọrun fun kootu ọhun.

Nigba ti ile-ẹjọ beere ọrọ lọwọ Atofarati, o ni oun ko jẹbi, eyi lo jẹ ki Amofin Fọlayan Emmanuel bẹbẹ fun beeli rẹ pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ.

Majisreeti-agba Abdulhamid Lawal gba beeli afurasi naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (N100,000) ati oniduuro meji niye kan naa, bẹẹ lo sun igbẹjọ sọjọ kọkandinlogun, oṣu to n bọ.

Leave a Reply