Ẹwọn n run nimu Daniel, ọmọọlọmọ lo fipa ba laṣepọ niluu Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

 

 

Afaimọ ki ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Daniel Lawrence, maa ṣẹwọn nitori ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ki ọmọ ọlọmọ mọlẹ ninu ileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣe beba, lagbegbe Irewọlede, niluu Ilọrin, to si ba a laṣepọ.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, tawọn ọlọpaa wọ ọ lọ sile-ẹjọ Magisreeti tilu Ilọrin, adajọ ti ni ki wọn sọ ọ satimọle ẹwọn l’Oke-Kura.

Akọsilẹ ọlọpaa fi han pe lati ẹka B’ Division to wa ni Surulere, niluu Ilọrin, ni wọn ti gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n gbogun ti ṣiṣe fayawọ eeyan, paapaa awọn obinrin ati ilokulo awọn ọmọde.

Gẹgẹ bi alaye ọlọpaa, Abilekọ Florence lo fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.

O ṣalaye pe lasiko ti ọmọbinrin naa n pada bọ lati ileewe ni Daniel lọọ dẹbuu rẹ lọna.

Wọn ni ṣe lo wọ ọmọdebinrin naa wọnu ileeṣẹ to ṣe n beba to wa lagbegbe naa, nibi to ti ki i mọlẹ, to si ba a sun ni tipa.

Wọn ni Daniel jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ṣugbọn ki wọn foju aanu wo oun.

Ọgbẹni Abubakar Issa to gbẹjọ ro fun ijọba ta ko beeli olujẹjọ naa. O ni ẹsun ifipabanilopọ jẹ ohun to buru jai, to si nilo ki ile-ẹjọ fọwọ agbara mu awọn to n ṣe iru ẹ ko le baa kasẹ nilẹ lawujọ.

Adajọ Mariam Fọlọrunṣhọ paṣẹ pe ki wọn gbe olujẹjọ naa lọ sọgba ẹwọn, o si sun ẹjọ naa si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii.

Leave a Reply