Ẹwọn n run nimu Kingsley, ọmọ ọdun mẹtala lo fipa ba laṣepọ ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Fun ẹsun fifipa ba ọmọ ọdun mẹtala kan laṣepọ, ile-ẹjọ Magisreeti kan niluu Ilọrin, ti paṣẹ ki ọkunrin kan, Kingsley Eze, ṣi lọ wa latimọle ọgba ẹwọn to wa ni Mandala lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Iwadii awọn ọlọpaa fi han pe lasiko ti ọmọbinrin naa lọọ tun ẹrọ amunawa (jẹnẹratọ) baba rẹ ṣe lọdọ Kingsley niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Ṣe ni afurasi naa fọgbọn tan an wọnu yara rẹ, to si fipa ba a laṣepọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni o ti jẹwọ ni tesan awọn pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Agbẹjọro ijọba, Adigun Adisa, ni ki ile-ẹjọ gbe e sahaamọ, nitori pe ẹsun ifipabanilopọ ki i ṣe ohun ti wọn kan le gba oniduuro rẹ ṣaa.

Ṣugbọn agbẹjọro olujẹjọ, Lawrence Ọpọọla, ta ko aba agbefọba naa, o ni onibaara oun ko ti i jẹbi ẹsun ta a fi kan an, afigba tile-ẹjọ ba paṣẹ bẹẹ.

Adajọ Shade Lawal gba ẹbẹ agbẹjọro ijọba naa, o si ni ki wọn maa gbe olujẹjọ ọhun lọ si ọgba ẹwọn, ko wa nibẹ titi di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Leave a Reply