Ẹwọn n run nimu Pasitọ Abayọmi yii o, ọmọ ọdun meje lo fipa ba lo pọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Atimọle awọn ẹṣọ alaabo ilu, iyẹn Nigeria Security and Civil Defence Corps, NSCDC, n’Ibadan,  lo ṣe e ṣe ki Ajihinrere Francis Abayọmi, ti ṣe  jẹ gbogbo iṣẹ ihinrere rẹ lati asiko yii di ipari oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, nitori bo ṣe fi tipa tikuuku laṣepọ pẹlu ọmọdebinrin ti ko ju ọmọ ọdun  meje lọ.

 

Baba ẹni ọdun mejidinlọgọta (58) yii la gbọ pe o fi ọgbọn alumọkọrọyi tan ọmọbinrin naa, Monday Dorcas, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri lọ si ojú-ọlọ́mọ-ò-tó-o, to si fi kinni nla fa ọmọọlọmọ labẹ ya nipasẹ ibalopọ.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, to lọ lọhun-un niṣẹlẹ ọhún waye l’Opoopona Kutamiti, lagbegbe Bódìjà, n’Ibadan.

Irin yẹnku yẹnku ti Dorcas rin lọ sile pẹlu ẹjẹ to kún gbogbo oju ara ẹ lo tu pasitọ laṣiiri nigba ti iya fi dandan le e pe ko jẹwọ ẹni to da ọgbẹ si i nibi kọlọfin ara.

Iya Dorcas, pẹlu awọn alabaagbe ẹ ko mọ oju ti wọn fi lọọ já bá pasitọ ti oun naa jẹ aladuugbo wọn nile. Bo tilẹ jẹ pe oluṣọ-aguntan naa ko ti i jẹwọ ẹṣẹ rẹ fawọn eeyan, sibẹ, awọn obi ọmọ naa ko fi ọ̀wọ̀ iṣẹ ihinrere to yan laayo wọ ọ ti wọn fi fa a le awọn agbofinro lọwọ.

Olu-ileeṣẹ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Agodi, n’Ibadan, ni wọn mu ẹjọ Francis lọ taara.

 

Lẹyin iwadii, Ọgbẹni Iskilu Akinsanya ti i ṣe ọga agba awọn ajọ NSCDC ko jẹ ko pẹ lọdọ wọn rara ti wọn fi pe e lẹjọ si kootu ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni Iyaganku, n’Ibadan.

Onidaajọ S.H. Adebisi ti i ṣe adajọ ile-ẹjọ Majisireeti ọhun ti waa paṣẹ pe ki wọn fi olujẹjọ iwa ọdaran naa pamọ si atimọle ajọ sifu difẹnsi titi di ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, nigba ti igbẹjọ naa yoo maa tẹsiwaju.

Leave a Reply