Ẹwọn n run nimu Yusuf o, ọmọ bibi inu ẹ lo binu ju sodo ni Badagry

Faith Adebọla, Eko

Eebu ati epe loriṣiiriṣii lawọn eeyan n ṣẹ le baba ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Fatai Yusuf, ni kootu, pẹlu bile-ẹjọ ṣe paṣẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, pe ki wọn sọ ọ si ahamọ ọgba ẹwọn na. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fibinu ju ọmọ bibi inu ẹ ti ko ju ọsẹ mẹfa pere lọ sinu odo, afigba tọmọbinrin naa ku somi.

Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, ọṣu kejila, ọdun ta a lo kọja yii (2020) ni wọn ni niṣẹlẹ naa waye lagbegbe Badagry, nipinlẹ Eko.

Nigba ti wọn n kawe ẹsun rẹ si i leti ni kootu Majisreeti to wa n’Ikẹja, Agbefọba, DSP Nurudeen Thompson, sọ pe ara ọmọ ikoko naa ko ya lọjọ iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn iya rẹ n ṣe ọrọ-aje kara-kata lọwọ ni ṣọọbu rẹ, boya ibinu bi iya ọmọ yii ko ṣe raaye bojuto ọmọ to n ṣojojo yii ni o, boya nnkan mi-in si kọ lu baba naa ni, wọn ni niṣe ni baale ile yii gbe ọmọbinrin naa mọra bii ẹni pe o fẹẹ gbe e lọ sileewosan tabi kẹmiisi (chemist) kan to wa laduugbo wọn, afi bo ṣe jẹ ọna odo adagun Ajanaku, ti ko fi bẹẹ jinna sile wọn lo dori kọ nigba to jade.

Wọn lọmọdekunrin kan to jẹ ẹgbọn ìkókó naa tẹle baba wọn, niṣoju ẹ si ni baba naa ṣe sọ ọmọ bibi inu ẹ to gbe dani ọhun sinu odo, bo tilẹ jẹ pe ẹgbọn ọmọ naa bẹ baba wọn pe ko ma ṣe bẹẹ, ko lọọ gbe aburo oun wa, ti baba yii ko si dahun.

A gbọ pe nigba to dele, niṣe lo sọ fun iya ọmọ naa pe oun ti gbe ọmọ wọn lọ sọsibitu kan, pe o n gba itọju lọwọ, ṣugbọn ẹgbọn oloogbe lo taṣiiri ohun to ṣẹlẹ, bo ṣe n rojọ lo n sunkun pe baba oun ti pa aburo oun, niya ọmọ naa ba figbe ta, ti wọn si lọọ fọrọ to awọn ọlọpaa leti ni tẹsan Badagry. Ẹsẹkẹsẹ ni wọn ti mu baba apaayan ọhun sọ sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ.

Atigba naa lawọn ọlọpaa ti n ṣe iwadii loriṣiiriṣii lori iṣẹlẹ aburu naa, abọ iwadii wọn lo gbe afurasi ọdaran yii dewaju adajọ lọjọ Wẹsidee yii.

Adajọ Majisreeti naa, Ọgbẹni P. E. Nwaka, ni oun o ti i fẹẹ gbọ alaye kan lẹnu afurasi ọdaran naa, o paṣẹ pe ki wọn ṣi sọ ọ sẹwọn to wa ni Ikoyi titi tawọn maa fi ri imọran gba latọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran, DPP. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji yii.

Leave a Reply