Ẹwọn ọdun mẹta ni adajọ ju Stephen si, oni POS lo lu ni jibiti

Monisọla Saka

Ile-ẹjọ to n ri si awọn ẹsun pataki kan to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, Ikẹja Special Offences Court, ti ju ọkunrin kan ti ko nisẹ lapa, ti ko si ni nnkan mi-in to n ṣe ju ko maa lu jibiti lọ, Stephen Chukwudi, sẹwọn ọdun mẹta. Oni POS lo lu ni jibiti ẹgbẹrun lọna mejidinlaaadọrun-un (88,000) Naira.

Aṣoju ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorilẹ-ede yii (EFCC), Ọgbẹni Ahmed Yerima, ṣalaye fun ile-ẹjọ pe olobo lo ta awọn pe awọn ọmọkunrin kan lu awọn eeyan ti wọn n fi ẹrọ ipọwo kekere, POS, ni jibiti, lagbegbe Ọbalende, nipinlẹ Eko.

O tẹsiwaju pe obinrin oni POS yii fowo ranṣẹ sinu akaunti olujẹjọ yii pẹlu asọyepọ laarin wọn pe yoo ko iye owo toun ṣe sinu akaunti rẹ le oun lọwọ ni kiṣi.

Ṣugbọn niṣe ni olujẹjọ fẹsẹ fẹ ẹ ni kete ti owo balẹ sinu akaunti rẹ, gbogbo akitiyan obinrin oni POS yii lati ri owo ẹ gba pada lo si ja si pabo.

Iṣẹlẹ naa lo ni o mu ki olupẹjọ waa fi ọrọ naa to awọn leti. Yerima ni gbara ti awọn gbọ nipa ọrọ naa nileeṣẹ awọn lawọn ti nawọ gan ọdaran yii lẹyin tawọn kọkọ ti akaunti rẹ, ti ko si lanfaani lati ri owo gba jade nibẹ. O ni iwa ọdaran ti ọkunrin yii hu ta ko abala kẹjọ iwe ofin to n ri si ẹsun ọdaran, ti ọdun 2006.

Bo tilẹ jẹ pe o rawọ ẹbẹ si kootu pe ki ọn ṣiju aanu wo oun, oun ko ni i ṣe bẹẹ mọ, sibẹ ẹwọn ọdun mẹta ni Onidaajọ Mojisọla Dada ran ọdaran naa fun ọna alumọkọrọyi to gba lu ẹni to ja lole ni jibiti.

Onidaajọ Dada sọ pe ile-ẹjọ yoo faaye beeli ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira, (150,000) silẹ fun olujẹjọ, ṣugbọn ti ko ba ti ni i le san an, ko lọọ fẹwọn ọdun mẹta jura.

Bakan naa lo tun paṣẹ pe ki ọdaran naa san deede iye owo to fi lu olupẹjọ ni jibiti, ko si fọwọ siwee pe oun yoo gbe iwa ọmọluabi wọ, oun ko si ni i rin ni regberegbe iwa ọdaran yoowu, ni kete toun ba ti jade lọgba ẹwọn.

Leave a Reply