Ewu nla ni eto Big Brother fun ọjọ iwaju awọn ọdọ wa – Ọọni Ogunwusi

Arole Oduduwa, Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ti kọminu lori iha ti awọn ọdọ orileede Naijiria kọ si lilu aluyọ lai ni eru ninu. Ọba naa sọ pe ọpọ ọdọ ni ọrọ aye wọn ko nitumọ si mọ, ohun to wu wọn ni wọn n ṣe.

Lasiko ti Ọọni Ogunwusi ko awọn ọdọ labẹ iṣakoso National Youth Council of Nigeria jọ laafin rẹ niluu Ileefẹ lati ṣayẹyẹ ayajọ awọn ọdọ lagbaaye tọdun yii lo ti sọ pe ti awọn ọdọ ba n lo asiko ti wọn n lo lori eto Big Brother Naija lori igbesi aye wọn, ki i se ibi ti orileede yii wa bayii lo maa wa.

Kabiesi sọ pe asiko ti to fun awọn ọdọ lati ronu, ki wọn gba ipenija lati de ipo adari, dipo ki wọn kan jokoo nibi kan sọrọ aleebu si awọn to n ṣakoso lorileede yii. O ni eeyan miliọnu mẹtadinlọgbọn pere ni wọn dibo lasiko idibo apapọ ilẹ wa to waye kọja, ṣugbọn eeyan miliọnu mẹtadinlọgọfa ni wọn dibo lasiko eto Big Brother Naija lọdun 2019.

Ọọni ṣalaye pe ẹdun ọkan ni eleyii jẹ fun oun nitori ṣe ni ọpọlọpọ ọdọ ro pe ki awọn ji lọjọ kan ki gbogbo nnkan si ti bọ sipo lorileede yii lai mọ pe awọn gan-an ni iṣẹ to pọ ju ninu ẹ.

Dipo Big Brother Naija, Ọba Adeyẹye ni ṣe ni ki awọn adari ẹgbẹ NYCN gbe eto kan kalẹ ti wọn yoo maa pe ni The Big Nigeria Reality Show, nibi ti awọn ọdọ yoo ti lanfaani lati ṣafihan ọpọlọ pipe ati ọgbọn inu ti Ọlọrun fi ta wọn lọrẹ.

Ninu ọrọ Minisita fun ọrọ awọn ọdọ ati ere-idaraya, Ọgbẹni Sunday Dare, ẹni ti Dokita Mariam Abdullahi ṣoju fun, o ni awọn ọdọ ni ipa nla lati ko ninu idagbasoke orileede yii, ati pe ijọba Aarẹ Buhari ko ni i kuna ninu ojuṣe rẹ lati mu igbelarugẹ ba ọdọ to ba ṣipa.

Bakan naa ni Gomina Oyetọla, ẹni ti kọmisanna fọrọ awọn ọdọ ati ere-idaraya, Ọgbẹni Yẹmi Lawal ṣoju fun, rọ awọn ọdọ lati ni itẹriba ki wọn le kọ ẹkọ lara awọn agba, ki o le baa rọrun fun wọn lati de ibi ti wọn n lọ.

Aarẹ awọn ọdọ lorileede yii, Sukubo Sara-Igbe Sukubo, dupẹ lọwọ Ọọni Ogunwusi, o si ṣeleri pe gbogbo imọran kabiesi lawọn yoo tẹle.

Ṣaaju ni ẹni to jẹ oludasilẹ ajọ Elizabeth Jack-Rich Aid Foundation ti rọ awọn ọdọ lati sa fun ẹgbẹ buburu, ki wọn si fọkan si ohun gbogbo ti yoo mu ki ọjọ iwaju wọn rọrun.

Leave a Reply