Ẹya ara ọkọ lawọn ọdọmọde yii maa n ji tu lọganjọ oru l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Aajin oru, tọwọ ti pa, tẹsẹ ti pa, ti kaluku n sun labẹ orule rẹ, lawọn gende mẹrin yii, Tochukwu Ucheagwu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Emmanuel Oyekanmi, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Ibama Emmanuel, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Bọlaji Bababunmi, ẹni ọgbọn ọdun, ati Ifeanyi Owoh, n rin kiri igboro, ti wọn n pa kubẹkubẹ lẹgbẹẹ awọn mọto ti wọn gbe sẹgbẹẹ titi ati niwaju ile, bẹẹ ni wọn n gba horo si horo, awọn ẹya ara ọkọ, ati nnkan ẹṣọ ti wọn lẹ mọ mọto ni wọn n ji tu tọwọ fi ba wọn lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, yii.

Awọn ọlọpaa ti wọn n rin kaakiri agbegbe Ojodu ati Berger ni wọn kẹẹfin awọn afurasi yii nitosi biriiji Ọtẹdọla, wọn ṣakiyesi pe irin ẹsẹ wọn gba ifura, ni wọn ba da wọn duro.

Nigba ti wọn yẹ ara ati baagi ti wọn gbe dani wo, wọn ba aake, ada, ọbẹ, atawọn irinṣẹ ti wọn fi n tu ẹya ara ọkọ nibẹ, bẹẹ ni wọn ri ẹya ara ọkọ Toyota, ti Nissan atawọn ọkọ mi-in ti wọn ji tu.

Wọn lawọn afurasi naa ti jẹwọ pe ọmọ oru laa ṣika lawọn, awọn lawọn n sọ mọto onimọto di korofo kilẹ too mọ, wọn si ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ to n ṣewadii lẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Panti, ni Yaba.

Bakan naa lọwọ tẹ awọn afurasi adigunjale marun-un mi-in loru ọjọ yii kan naa, awọn ero ati onimọto lawọn eleyii n ja lole nibudokọ to wa ni Koṣọfẹ, lọna marosẹ Ketu si Ikorodu. Awọn ọlọpaa teṣan Ketu ni wọn mu wọn, ẹyin tọwọ ba wọn tan ni wọn juwe awọn meji kan ti wọn jọ n ṣiṣẹẹbi wọn ọhun, ọwọ si ba awọn naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pe ẹni to kere ju laarin wọn jẹ ọmọọdun mejidinlogun pere, nigba tẹni to dagba ju jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn.

Wọn ti rọ gbogbo wọn da si Panti, ni Yaba, fun iwadii to lọọrin. Lẹyin naa ni wọn maa kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.

Leave a Reply