Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ẹgbẹ Yoruba parapọ ni Kwara, rọ ijọba apapọ ko samulo iwe ofin ọdun 2014, ko da ipinlẹ Kwara pada si ẹya Yoruba tori pe wọn n fi ẹtọ wọn dun wọn.
Nigba ti ẹgbẹ naa n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipade akọroyin kan to waye lagbegbe Ganmọ, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ẹni to jẹ adari ẹgbẹ jake-jado ipinlẹ naa, Samuel Adewọle, kọ apilẹkọ kan ti Oloye Jayeọla Ọmọtọsọ si ka a. Nibẹ ni wọn ti sọ pe lẹyin ti wọn ti pin ipinlẹ Kwara si ko ṣeku, ko ṣẹyẹ ni ẹya Yoruba ko ti ri ẹtọ rẹ gba nipinlẹ naa tori pe awọn Fulani ni wọn n jẹ gaba.
O tẹsiwaju ninu apilẹkọ naa pe ijọba ibilẹ mẹrindinlogun lo so Kwara ro, to si jẹ pe mejila ninu rẹ, ede Yoruba ni wọn n sọ lẹnu, ti ijọba ibilẹ meji si jẹ ẹya Nupe, nigba ti meji to ku jẹ iran Baruba, ẹya Baruba yii lo jọ n pin oye ọba jẹ laarin awọn ẹya Yoruba Kwara ati Ọyọ. Wọn ni ohun ti ko bojumu ni bi wọn ṣe n pe awọn ijọba ibilẹ marun-un kan, Iwọ-Oorun Ilọrin, Ila-Oorun Ilọrin, Asa ati Moro, ni Emirate, ti ko si si ọba Fulani kankan to n jọba wọn lẹyin Ẹmia ilu Ilọrin, ati pe Afọnja ti wọn ṣeku pa lo ṣokunfa gbogbo rẹdẹ-rẹdẹ ti oju Yoruba n ri ni Kwara bayii. O fi kun un pe ọrọ naa ṣi wa nile-ẹjọ lori pe ki wọn da Kwara pada si Guusu Iwọ-Oorun Naijiria.
Adewọle tẹsiwaju pe iwe ofin ọdun 1999, ti wọn se atunse rẹ ko faaye ipin dọgbandọgba silẹ fun gbogbo ẹya ni Naijiria, ti wọn o ba si fẹ ki Naijiria doju de patapata, wọn gbọdọ fun ẹya kọọkan lẹtọọ rẹ, ki onikaluku si seto ọlọpaa agbegbe rẹ, eyi ti yoo mu ki eto aabo duroo re nilẹ yii, tori pe ko si iyemeji pe Naijiria ti fẹẹ doju de.
Ni igunlẹ iwe apilẹkọ naa, wọn ni Yoruba Kwara ti setan bayii fun orile-ede Yoruba tabi Orile-ede Oodua, nigba ti ẹtọ Yoruba ko tẹ ẹ lọwọ.
Lara awọn ẹgbẹ to pejọ sibi ipade naa ni ẹgbẹ ‘Afọnja Group’, ‘Ọladerin Cultural Group’, ‘Ẹgbẹ ọmọ ibilẹ Igbomina’ Ekiti Kwara’, ‘Oodua People’s Congress’, ‘Sao Awọnga’ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn ọba alaye to wa nijokoo ni Ọba ilu Jẹbba, HRM Alaaji Abdulkadir Alabi Adebara, aṣoju Ọhọrọ Sao, Ọba Bamidele Adegbitẹ, Imaamu agba tilẹ Yoruba niluu Ilọrin, Alaaji Abdulraheem ati Ajakijipa Sao, naa wa ni ijokoo lọjọ naa, ti wọn si ni gbogbo wọn ni wọn ṣoju ọmọ Yoruba ni Kwara, ti wọn si gba ẹnu wọn sọrọ.