Faith Adebọla
Yooba bọ, wọn ni a ki i dọbalẹ ka ni’na loju. Asiko yii o jọ asiko tawọn oloṣelu n ni ina loju rara, asiko arọwa ati ẹbẹ ni, pe kawọn araalu, paapaa ju lọ awọn ọdọ, le ṣatilẹyin fun wọn, ki wọn dibo fun wọn, niṣe ni oludije funpo gomina kan tiẹ kuku fi ikunlẹ bẹẹ, ọpọ wakati lo fi wa lori ikunlẹ, bẹẹ ko sẹni to da a kunlẹ o, niṣe lo n parọwa sawọn oludibo pe ki wọn dibo foun.
Ọgbẹni Peter Mbah, oludije funpo gomina ipinlẹ Enugu, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, lo gbe itiju ta l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta yii, lasiko to lọọ polongo ibo fawọn ọdọ ipinlẹ naa.
Ṣe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii, leyii ti ko ju ọjọ mẹta pere lọ mọ, ni ireti wa pe eto idibo sipo gomina yoo waye lawọn ipinlẹ mọkandinlọgọn kaakiri orileede yii, nigba ti tawọn aṣofin ipinlẹ yoo waye lorigun mẹrẹẹrin Naijiria lọjọ kan naa.
Amọ, bi esi idibo sipo aarẹ ṣe lọ si ti jẹ ki ọpọ oludije ko ọkan soke, tori ibi ti awọn kan foju si lara wọn, ọna ko gbabẹ.
A gbọ pe oludije yii ṣabẹwo airotẹlẹ si ayẹyẹ ọlọdọọdun kan tawọn ọdọ naa maa n ṣe ti asiko aawẹ Kirisitẹni ba ti wọle, iyẹn Ugwu Di Nso Annual Youth Lenten Retreat, pẹlu erongba lati bẹ wọn pe ki wọn ṣatilẹyin foun ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP. Bẹẹ lo ko ọpọ ọti ẹlẹridodo ati ipapanu wa, o ha a fun wọn lati fa oju wọn mọra, o ṣe tan, bẹnu ba jẹ, oju aa ti, bawọn agba ṣe n sọ.
Amọ awọn ọdọ yii ta ku, niṣe ni wọn n pariwo, ‘Obi, Obi, Lebọ, Lebọ ni o’, iyẹn orukọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party.
Loju-ẹsẹ ni oludije yii fikunlẹ ge e, ko tiẹ wo ti aṣọ aala funfun kinniwin to wa lọrun ẹ, o bẹrẹ si i bẹ wọn pe ki wọn jọọ, ki wọn wo oun ṣe laaanu, o si loun o ni i dide lori ikunlẹ, ibẹ lo kunlẹ si fun ohun to ju wakati kan lọ, sibẹ ko jọ pe awọn to n ba sọrọ fẹẹ gbọ tiẹ rara.
Nigbẹyin, oludije naa lọ, awọn ọdọ si n ba ayẹyẹ wọn lọ. Boya ẹbẹ ati ikunlẹ rẹ wọ awọn ọdọ naa leti abi wọn o ri tiẹ ro, ọjọ idibo ni esi arọwa rẹ yoo jade, nigba ti wọn ba sọ abajade eto idibo sipo gomina ipinlẹ naa.