Eyi lawọn ohun ti ma a ṣe ti mo ba di aarẹ Naijiria-Kwankwanso

Ọlawale Ajao, Ibadan

Oludije fun ipo aarẹ orileede yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP), Alhaji Rabiu Kwankwaso ti fi awọn ọmọ Naijiria pe oun yoo fopin si iṣoro ọwọngogo epo ti gbogbo ọmọ Naijiria n koju lọwọlọwọ bayii ti oun ba wọle idibo to n bọ gẹgẹ bii aarẹ orileede yii.

Nibi apero ti awọn igbimọ to n ja fun idagbasoke ẹkun Iwọ-Oorun Guusu ilẹ yii, iyẹn South-West Development Stakeholders Forum gbe kalẹ fawọn to n dupo aarẹ ilẹ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ti sọrọ naa ni Gbọngan Jogor Centre, to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan.

Kwankwaso, ẹni to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Kano sọ pe “Ta a ba n sọrọ nipa ọwọn epo, iwa ibajẹ ati iwa ajẹbanu lo n fa a. Lara iwa ibajẹ to n mu epo wọn ni owo iranwọ ti ijọba sọ pe awọn n san lori epo. A si maa fopin si gbogbo iwa ijẹkujẹ to n mu ki epo wọn. Ma a ri i daju pe awọn ẹbu ifọpo ta a ni lorileede yii n ṣiṣẹ.

Nigba to n sọrọ lori aṣeyọri ẹ lasiko to wa nipo gomina ipinlẹ Kano ati ohun to ni lọkan lati ṣe nipo ijọba, agba oṣelu naa sọ pe “emi o nigbagbọ ninu aroye ti awọn ijọba kan maa n sọ pe “ko sowo, ko sowo”, owo wa ninu ijọba. Mo ti ṣe e nigba ti mo wa ni gomina, a ro awọn eeyan lagbara daadaa.

“Laarin ọdun mẹjọ ti mo fi ṣejọba ni mo ya miliọnu kan Naira (₦1m) silẹ fun irolagbara awọn obinrin. A maa n mu ọgọọgọrun-un obinrin fun eto ẹkọṣẹ ọwọ loṣooṣu.

“Ma a seto idanwo Wayẹẹki ọfẹ fawọn akẹkọọ. Ọdun mẹrin lakẹkọọ to ba yege idanwo JAMB maa lanfaani lati fi esi idanwo yẹn wọle sileewe giga.

“Ma a ko awọn alumajiri to n ṣe baara kiri igboro kuro nilẹ. A maa ran awọn ọdọ wọnyi lọ sileewe tabi ka kọ wọn niṣẹ ọwọ”.

Bakan naa lo ṣeleri lati pese eto ilera ọfẹ, paapaa fawọn obinrin. Bẹẹ lo ṣeleri eto ẹkọ ọfẹ ati eto igbaye-gbadun fun gbogbo ọmọ Naijiria bi oun ba wọle idibo sipo aarẹ ilẹ yii.

Ṣaaju lọkan ninu awọn igbimọ to ṣagbekalẹ eto naa, Dokita Dokita Muyiwa Bamgbose, ti sọ fun oludije funpo aarẹ naa loju gbogbo aye pe awọn ko tori owo gbe eto naa kalẹ, nitori naa, awọn ko beere owo tabi gbowo lọwọ eyikeyii ninu awọn oludije to kopa nibi eto yii bi ko ṣe pe ki kaluku ba ara wọn sọ ootọ ọrọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Alaga igbimọ to ṣagbekalẹ eto naa, Ọgbẹni Alao Adedayọ sọ pe “a mọ-ọn-mọ ma pe awọn lọbalọba atawọn eeyan to lookọ lawujọ sibi eto yii ni, awọn eeyan wa, awọn iyalọja, iyalaje, oniṣẹ ọwọ, oniṣowo ati bẹẹ bẹẹ lọ la pe lati waa fojurinju pẹlu awọn to n dije dupo aarẹ.

“A n ṣe eyi ki ẹyin araalu le mọ pe ẹyin naa ni ipa lati ko ninu ọrọ idagbasoke orileede yii, paapaa, ilẹ Yoruba tiwa nibi.”

Adedayọ, to jẹ oludasilẹ iweeroyin ALAROYE fi kun un pe pataki eto itakurọsọ pẹlu awọn oludije fun ipo aarẹ wọnyi ni lati le maa ran awọn to wa nipo ijọba leti awọn ileri ti wọn ba ṣe faraalu lasiko ipolongo idibo wọn.

Lara awọn oludije dupo aarẹ ilẹ yii ti igbimọ South-West Development Stakeholders Forum ti gbalejo ṣaaju ni Alhaji Atiku Abubakar (PDP); Ọmọyẹle Ṣoworẹ (AAC), Kọla Abiọla (PRP) Ati Ọmọọba Adebayọ Adewọle (SDP).

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin, oṣu yii, ni igbimọ naa yoo gbalejo oludije funpo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi.

Leave a Reply