Faith Adebọla
Ko sẹni to de ayika ile-ẹjọ giga akanṣe ilu Eko, iyẹn Special Offences Court, to wa niluu Ikẹja, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ti ko ni i mọ pe igbẹjọ pataki kan n lọ lọwọ, latari b’awọn ẹṣọ alaabo ṣe duro wamuwamu, ti ọkọ ọlọpaa, ọkọ ẹlẹwọn, ọkọ adani awọn lọọya kun gbogbo ayika kootu naa fọfọ.
Ọjọ yii ni igbẹjọ tẹsiwaju lori awọn ẹṣun iwa ajẹbanu, ṣiṣi agbara lo, jibiti lilu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku ti wọn fi kan ọga agba tẹlẹri fun banki apapọ ilẹ wa, Central Bank of Nigeria, Alagba Godwin Emefiele, lakọtun. Owo ti wọn tọpasẹ rẹ, ti wọn ni Emefiele ko jẹ pin si apa meje, ọkan ni biliọnu mẹrin aabọ dọla ($4.5b), omi-in ni biliọnu mẹta din diẹ owo dọla ($2.8b).
Apa meji ni igbẹjọ ọjọ naa pin si. Ni nnkan bii aabo mẹsan-an kọja iṣẹju diẹ ti igbẹjọ kọkọ waye, gbogbo atotonu da lori ẹbẹ ti agbẹjọro to ṣoju fun Emefiele, Amofin agba Abdulakeem Ladi-Lawal, bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn fun onibaara oun ni beeli, ko le maa tile waa jẹjọ rẹ, tori akata ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, iwa ajẹbanu ati jibiti lilu nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ni afurasi naa wa, latigba ti wọn ti mu un lọsẹ meji sẹyin, ki wọn too kọkọ foju rẹ bale-ẹjọ lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin yii, tile-ẹjọ naa si paṣẹ pe ko ṣi wa lakata awọn EFCC na.
Nigba ti Adajọ Rahman Oshodi n gbe idajọ rẹ lori beeli kalẹ, o ni oun yọnda beeli fun Emefiele, ni owo ti iye rẹ jẹ aadọta miliọnu Naira (N50m), o si gbọdọ ni oniduuro meji, ti wọn niṣẹ to ṣee tọka si lọwọ, ọkọọkan wọn gbọdọ ni aadọta miliọnu Naira (N50m). Bakan naa, wọn si tun gbọdọ niwee-ẹri ‘mo sanwo ori mi funjọba Eko’, lati ọdun mẹta sẹyin, ati iwe idanimọ pe ojulowo ọmọ Eko ni wọn.
Ni ti Ọgbẹni Henry Isioma Omoile, toun naa n jẹjọ pẹlu Emefiele, adajọ yọnda beeli foun naa, amọ nitori afurasi yii ṣi n jẹjọ lọwọ niwaju Onidaajọ Olufunkẹ Sule-Hamzat, tile-ẹjọ giga kan to wa lagbegbe Yaba, ti wọn si ti fun un ni beeli miliọnu kan Naira atawọn ẹlẹrii meji, wọn ni iyẹn naa ti to foun lati gba beeli lori ẹjọ tuntun yii.
Eyi ni wọn ṣe ti adajọ fi kede isinmi ranpẹ, o ni ki gbogbo wọn pada si kootu laago mejila ọsan ọjọ Furaidee, ti igbẹjọ yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu lori awọn ẹsun ti EFCC tẹ pẹpẹ rẹ siwaju ile-ẹjọ.
Nigba taago mejila lu, adajọ pada wọnu kootu, wọn si pe Emefiele boode sinu akolo igbẹjọ. Kootu alawọ eeru ati ṣẹẹti kan lo wọ, ko de tai, bẹẹ ni ko wọ awo oju rẹ, amọ adajọ yọnda fun un lati wa lori ijokoo ninu akolo naa.
Agbẹjọro EFCC, Amofin agba Rotimi Oyedepo, pe ọkan ninu awọn ẹlẹrii mẹtalelọgbọn (33) ti wọn lawọn ti pese silẹ lati jẹrii ta ko Emefiele, jade, Monday Osasuwa lorukọ ọkunrin naa, oṣiṣẹ Banki apapọ ni.
Ọkunrin yii ṣalaye fun kootu pe oun mọ Emefiele bii ẹni mowo, ọga oun ni, o ni banki Zenith Bank, lawọn ti kọkọ pade, nigba ti wọn gba oun siṣẹ nibẹ gẹgẹ bii akolẹta lọdun 2001, iyẹn Dispatch Rider, ti Emefiele si jẹ ọga agba banki Zenith nigba yẹn.
O ni nigba ti Emefiele di ọga agba banki apapọ (CBN), ni oun naa tẹle e, ti wọn si gba oun siṣẹ ni CBN, lọdun 2014.
O jẹwọ pe lọdun 2020, ọga oun, iyẹn Emefiele, fi nọmba foonu kan ṣọwọ soun lori ikanni Wasaapu, o ni koun ba onitọhun sọrọ tori oun maa lọọ gba nnkan kan waa foun lọwọ rẹ.
O ni: “Nigba ti mo pe ẹni yẹn, Mista Mohil, o ni ọdọ oṣiṣẹ oun kan, Mista Raja, ni mo ti maa lọọ gba ẹnfiloopu kan fun ọga mi, wọn juwe ọfiisi Raja fun mi, ni ọna Adeola Ọdẹku, l’Erekuṣu Eko lọhun-un, nigba ti mo si debẹ, Raja fun mi ni ẹnfiloopu kan to wu benbe, o ni ki n ṣi i, owo lo wa ninu rẹ, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un owo dọla, ($100,000). Nigba ti mo si sọ fun Emefiele, o ni ki n lọọ mu un fun Henry Isioma Omoile, tori ilegbee Emefiele lo n gbe.”
Ọkunrin yii tun ṣalaye pe aimọye igba loun ti lọọ ba Emefiele gbowo bẹẹ, Henry yii si loun maa n jiṣẹ fun toun ba de, o loun ko le ka iye igba toun gba owo tabi ṣẹẹki fun Emefiele, amọ owo to pọ ju toun gba lẹẹkan toun ṣi ranti daadaa ni ($1m), miliọnu kan dọla, oun tun gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un mẹjọ aabọ dọla ($850,000), lẹẹkan, oun gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un meje aabọ ($750,000), lẹẹkan, oun gba ẹgbẹrun lọna irinwo ($400,000), lẹẹkan, kaaṣi ni gbogbo eyi toun darukọ yii, awọn ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un tabi lọna igba ko si lonka.
O ni ọga oun ko f’oun ni kọbọ ri ninu owo wọnyi o, oun ko si gba ohunkohun ju salari ati ẹtọ oun ni banki naa lọ.
Ni ti ṣẹẹki, Osasuwa ni Emefiele maa n ran oun lọọ gba ṣẹẹki ni ileeṣẹ MINL kan to wa lagbegbe Isọlọ, l’Ekoo. Dumies Oil and Gas Limited, ni wọn maa n kọ sori ṣẹẹki naa.
Wọn beere lọwọ ẹlẹrii yii boya o ti ṣalaye gbogbo ọrọ yii fun Emefiele, o si loun ti ṣe bẹẹ nigba tawọn foju-rinju lakata EFCC, ko si ja oun niyan rara, amọ o ni ki i ṣe oun loun ba gba awọn owo naa.
Adajọ ni ki Agbẹjọro Emefiele, Amofin Ladi-Lawal, beere ohun to ba fẹẹ beere lọwọ ẹlẹrii yii, amọ niṣe ni Amofin naa ni kile-ẹjọ foun laaye lati kọkọ ṣatupalẹ awọn iwe-ẹri kan ti wọn ṣẹṣẹ ko foun, ati pe oun fẹẹ ba onibaara oun fikun lukun.
Ẹbẹ yii ko ṣetẹwọgba fun Adajọ Rahman Oshodi. Adajọ ni, “Pẹlu ẹlẹrii mẹtalelọgbọn ta a ṣi maa gba ẹri lẹnu ọkọọkan wọn, ọdun wo waa la fẹẹ pari igbẹjọ nigba ti iwọ amofin ba tun n foni-doni-in fọla dọla lori ibeere ayẹwo ẹlẹrii? Ko saaye fun ifakoko ṣofo. Afurasi lẹtọọ lati gba idajọ rẹ lasiko, a o le sọ ẹjọ yii di eyi to falẹ jan-an-ran jan-na-ran bii okun kanga.”
Nigbẹyin, Ladi-Lawal beere ibeere ṣoki, bo tilẹ jẹ pe o ni ko rọrun foun rara.
Lopin atotonu, adajọ sun igbẹjọ to ku si ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọjọ kẹta, ọjọ kẹsan-an ati ikẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii. O ni ki EFCC ma jafara lati ko awọn ẹlẹrii wọn wa, ki Emefiele naa si gbaradi lati ko awọn ẹlẹrii mẹjọ to loun ni silẹ.
Lẹyin ti adajọ dide, ti igbẹjọ pari, Emefiele ati awọn lọọya rẹ gbogbo fori kori fun ọpọlọpọ iṣẹju, wọn si n sọrọ wuyẹwuyẹ laarin ara wọn.