Eyi lawọn ohun to ṣẹlẹ nibi aṣekagba ọdun Ọṣun Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹsẹ ko gbero nibi aṣekagba ọdun Ọṣun Oṣogbo, eyi to maa n waye lọdọọdun nipinlẹ Ọṣun.

Tọdun yii paapaa ko yatọ si bi wọn ṣe maa n ṣe e. Ọpọ eeyan lati awọn orileede kaakiri agbaye ni wọn peju sibẹ. Bakan naa lọrọ ri nilẹ Naijiria, kaakiri origun mẹrẹẹrin orileede yii ni awọn olubọ Ọṣun atawọn to maa waa tọrọ ohun kan tabi omiiran lọdọọdun ti peju sibẹ. Ọpọ awọn eeyan ni wọn lọ seti odo yii, ti wọn si n gbadura, ti wọn n tọrọ awọn ohun ti wọn fẹ lọdọ Yeye Ọṣun.

Bẹẹ ni ọpọ eeyan ko kẹẹgi dani, ti wọn n bu omi odo naa, eyi ti wọn gbagbọ pe o wa fun iwosan loriṣiiriṣii.

Ọpọ eeyan lo wọ tẹle arugba Ọṣun ti ọdun yii, lẹni to saaba maa n jẹ obinrin ti ko ti i mọ ọkunrin. Bo ṣe n ru igba naa lọ si ojubọ Ọṣun ni ọpọ eeyan n tẹle, bi wọn ṣe n lulu, bẹẹ ni wọn n jo ninu aṣọ funfun nẹnẹ.

Nigba to n sọrọ nipa ọdun Oṣogbo ti ọdun yii, Aarẹ ẹgbẹ awọn ẹlẹsin iṣẹṣe, Traditional Religion Worshippers Association (TRWASO) ẹka ti ipinlẹ Ọṣun, Dokita Oluṣeyi Atanda, sọ pe ọwọ tijọba orileede yii fi mu ọrọ aṣa ko bojumu to.

O ni idi ti gbogbo nnkan to jọ mọ aṣa ko fi tẹsiwaju ju bo ṣe yẹ ko ri lorileede Naijiria ko ṣẹyin bijọba ko ṣe fi ọwọ gidi mu un, ki wọn si na owo le ẹka naa.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ nibi aṣekagba ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo ti ọdun 2024 to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, Atanda ṣalaye pe owo tijọba n ya sọtọ fun ẹka aṣa ninu bọjẹẹti ti n kere ju.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’Orileede Arab, ṣamojuto aṣa wọn lo jẹ ko di ibi ti awọn eeyan n ya lọ lọdọọdun, bẹẹ naa si lọrọ ri fun awọn orileede miiran tawọn eeyan maa n lọ.

‘’Ọpọlọpọ anfaani lo wa nidii ọrọ aṣa, to jẹ pe tijọba apapọ ba le ṣamojuto rẹ daadaa, yoo di orisun nla ti owo yoo maa gba wọle labẹnu sapo ijọba’’.

Ninu ọrọ tirẹ, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ẹni ti Akọwe ijọba, Alhaji Tesleem Igbalaye, ṣoju fun, ṣalaye pe ijọba oun ko ni i kasarẹ lori erongba rẹ lati mu ajinde ba gbogbo awọn ibudo aṣa atawọn nnkan isẹmbaye kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

Adeleke ṣalaye pe gbogbo awọn nnkan to ni i ṣe pẹlu imugbooro eto ọrọ-aje nijọba oun n mojuto bayii, niwọn igba to si jẹ pe ipinlẹ Ọṣun ni orirun iran Yoruba, iṣelọjọ awọn nnkan amuyangan iran naa jẹ ijọba logun.

O tẹ siwaju pe gbogbo awọn oludaṣẹsilẹ ti wọn ni i ṣe pẹlu nnkan aṣa ati iṣẹnbaye nijọba n fọwọsowọpọ pẹlu, ki ipinlẹ Ọṣun baa le di ojuko fun aṣa lorileede yii.

Lara awọn ti wọn wa nibi aṣekagba ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo ti ọdun 2024 ni Olowu ilu Kuta, Araba Awo ti ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ọṣundagbonu Ẹlẹbuibọn, Àgbọ́ngbọ́n Awo ti ilu Oṣogbo, atawọn oniṣẹṣe kaakiri orileede Naijiria ati l’Oke-Okun.

Leave a Reply