Eyi le o, ajinigbe lawọn gende meji kan fẹẹ mu ti wọn fi ku sodo n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii, ni iṣẹlẹ kayeefi kan ṣẹ niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Ajinigbe kan ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ lo ji ọmọ kekere kan gbe ni agbegbe Amilẹgbẹ, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ilọrin, wọn gba a mu, wọn si gba ọmọ naa lọwọ ẹ. Ṣugbọn ni kete ti wọn fẹẹ maa fiya jẹ ẹ lo fere ge e, lawọn gende meji ti a o ti i mọ orukọ wọn ba gba tẹle e, nise ni ajinigbe naa bẹ sinu odo Amilẹgbẹ to wa ni agbegbe naa, lawọn ọkunrin meji ọhun ba bẹ tẹle e, ṣugbọn niṣe ni wọn dawati ninu odo.

Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn ti n wa wọn ninu odo ni wọn pada yọ oku wọn jade. ALAROYE gbọ pe ọdaran ajinigbe naa mọ odo o wẹ daadaaa, eyi lo fa a ti wọn ko fi ri i mọ.

Leave a Reply