Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Iya ẹni aadọta ọdun kan, Adeniyi Daramọla, ti n rọjọ ẹnu ẹ nile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ado-Ekiti bayii, latari ẹsun pe o gba abẹtẹlẹ lọwọ awọn mọlẹbi Ṣeun Ọlanrewaju, ọmọdekunrin ọmọọdun mejidinlogun ti wọn lo fipa ba ọmọ-ọmọ rẹ ti ko ju ọmọ ọdun mẹta laṣepọ.
Ṣaaju lawọn ọlọpaa ti kọkọ mu obinrin yii sahaamọ lori ẹsun ọhun, wọn ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira lo gba lọwọ awọn mọlẹbi afurasi ọdaran, Ṣeun. Awọn ọlọpaa ti gba owo naa pada lọwọ obinrin ọhun gẹgẹ bii ẹsibiiti.
Nigba tawọn ọlọpaa wọ ọ dele-ẹjọ gẹgẹ bi iwe ẹsun ti wọn ka ṣe fihan, wọn ni ni deede aago mẹwaa ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, ọdun yii, lobinrin naa gba owo ọhun pe ko ba awọn daṣọ aṣiri bo afurasi ọdaran to ṣaṣemaṣe yii, wọn ni ko pa awọn sile, ko ma pa awọn sita.
Agbefoba, Insipẹkitọ Elijah Adejare, tun ṣalaye siwaju pe ẹsun yii tẹwọn, o si ni ijiya to gbopọn labẹ iwe ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ekiti n lo, eyi ti wọn kọ lọdun 2012.
Ṣugbọn obinrin yii sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa, o loun ni alaye ati arojare lori ẹ.
Onidaajọ Temi Daramọla fun obinrin yii ni iyọnda beeli ẹgbẹrun mẹwaa naira, pẹlu oniduuro kan, o si sun igbẹjọ to n bọ si ogunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2021.