Eyi le o, lọjọ kan ṣoṣo, Korona paayan mẹta l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gende Ọlọrun mẹta lajakalẹ arun Korona pa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. O tun sọ eeyan mọkandinlaaadọrin (61) mi-in di alaigbadun ara wọn.

Eyi jẹ yọ ninu ikede abajade ayẹwo arun Korona ti ajọ NCDC ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee.

Gẹgẹ bi akọsilẹ esi ayẹwo ọhun, ipinlẹ Eko lawọn ti kokoro arun yii mu lọjọ naa ti pọ ju lọ gẹgẹ bo ṣe saaba maa n waye lojoojumọ. Eeyan mejilelaaadoje (212) ni jagunlabi tun fọwọ ba l’Ekoo lọjọ naa.

Ipinlẹ Ọyọ ni Korona ti ṣoṣẹ ju lọ lọjọ naa pẹlu bo ṣe jẹ pe eeyan mọkandinlaaadọrin (69) lo mu nibẹ, nigba ti awọn to mu nipinlẹ Niger to ṣe ipo kẹta ninu akọsilẹ ọjọ Tusidee ọhun jẹ mọkandinlaaadọta (49).

Bi kokoro arun ti wọn n pe ni COVID-19 yii ṣe n fojoojumọ pọ si i jake-jado orileede yii ni kinni ọhun tubọ n burẹkẹ nipinlẹ Ọyọ tayọ awọn ẹgbẹ ẹ lorileede yii.

Lati inu oṣu kẹta ọdun 2020 yii ti ajakalẹ arun Korona ti wọ Naijiria, Ọyọ yii kan naa ni ipinlẹ to tayọ Eko lọjọ kan ri, iyẹn Jimọ ọsẹ to kọja, nigba iye eeyan ti Korona mu ni ipinlẹ Ọyọ lọjọ naa pọ ju Eko to ti maa n wa nipo kin-in-ni ṣaa tẹlẹ lọ.

Apapọ eeyan to ti fara kaaṣa kokoro arun yii ni ipinlẹ ọhun bayii ti di bii ẹgbẹrun mẹta. Iyẹn l’Ọyọọ si ̣ṣe jẹ ipinlẹ kẹta to ni akọsilẹ ajakalẹ arun Korona julọ jakejado orileede yii.

 

 

 

Leave a Reply