Eyi le o, Peter Obi ko ẹri pelemọ siwaju ile-ẹjọ lati ta ko Tinubu ati APC

Faith Adebọla

Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Ọgbẹni Peter Obi, ati ẹgbẹ oṣelu naa, ti tẹpẹpẹ ẹri pelemọ kan siwaju igbimọ to n gbọ awuyewuye to su yọ lasiko idibo aarẹ ti ọdun 2023, iyẹn Presidential Election Petition Tribunal (PEPT) eyi ti ijokoo rẹ n lọ lọwọ nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan niluu Abuja ti i ṣe olu-ilu ilẹ wa. Igbimọ naa si ti gba awọn ẹri naa wọle.

Awọn ẹri wọnyi, eyi ti wọn ṣe adipọ rẹ nipele nipele sinu iwe bamba kan, ti wọn si le awọn iwe naa kalẹ bii ẹni patẹ ọja siwaju igbimọ onidaajọ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa yii, lasiko ti igbẹjọ tun waye lori ẹjọ ti Peter Obi ati Labour Party pe ta ko abajade esi idibo ati iyansipo Aarẹ Bọla Tinubu, eyi ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, kede rẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Lọtẹ yii, awọn ẹsibiiti ti Peter Obi ati Labour Party ko wa si kootu ọhun nipasẹ awọn agbẹjọro wọn agba, Amofin Peter Afọba, jẹ kidaa awọn ẹda iwe esi idibo ati akọọlẹ ti INEC ṣe lasiko ti esi idibo naa waye, eyi to fẹri han pe ọpọ ibi ni idibo ko ti waye rara, tabi ti wọn ti wọgi le esi idibo rẹ, lati fihan pe esi idibo ti INEC kede rẹ fun ipo aarẹ to kọja yii ko peye rara, o si ni ọpọ magomago ninu.

Lara awọn ẹri ọhun la ti ri fọọmu esi idibo EC40GPU ati EC40G1, to ṣakopọ orukọ awọn oludibo lawọn ibudo idibo ati ni ijọba ibilẹ kọọkan ti idibo ko ti waye rara, tabi ti wọn ti wọgi le esi idibo wọn.

Ẹri naa kan ibudo idibo marundinlaaadọta nijọba ibilẹ mẹwaa nipinlẹ Niger, ibudo idibo mẹtalelogun nijọba ibilẹ meje to wa nipinlẹ Ọṣun, ibudo idibo mẹtadinlogun lati ijọba ibilẹ mẹta nipinlẹ Edo, ati ibudo idibo mejilelaaadọta nijọba ibilẹ marun-un lati ipinlẹ Sokoto.

Bẹẹ lawọn olupẹjọ yii tun ko ẹri lati ibudo idibo mi-in gbogbo kaakiri orileede yii jọ, ile-ẹjọ naa si ti gba gbogbo rẹ wọle lati ṣatupalẹ wọn, ki wọn si pinnu boya awọn ẹri naa kin awijare olupẹjọ lẹyin.

Lafikun si i, awọn olupẹjọ yii tun taari akọsilẹ ati iroyin ti ajọ INEC ti gba wọle, eyi to fi han kedere pe ọpọ magomago ati eru idibo lo ṣẹlẹ lawọn ibudo idibo kan kaakiri ipinlẹ Edo, Niger, Ọṣun atawọn ibomi-in, lasiko ti eto idibo aarẹ ọhun waye, eyi to mu kawọn olupẹjọ naa pẹjọ pe awọn ko fara mọ bi INEC ṣe kede Tinubu gẹgẹ bii olubori eto idibo ọhun.

Ni bayii, igbimọ naa ti sun igbẹjọ to kan si ọla, ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa yii, lati maa tẹsiwaju lori ẹsun yii.

Leave a Reply