Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nigba ti iroyin iku Oshọkọya Deborah Ayọmikun gbode kan lọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ yii, iyẹn akẹkọọ to wa nipele aṣekagba nileewe giga Tai Solarin University Of Education (TASUED), Ijagun, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe ọmọ naa gbe majele jẹ nitori pe o kuna ninu idanwo aṣekagba ni. Ṣugbọn awọn alaṣẹ ileewe naa ti sọrọ, tiwọn si ta ko ohun tawọn aye n gbe kiri.
Alukoro TASUED, Abilekọ Ayọtunde Odubẹla, ṣalaye pe loootọ ni ọmọbinrin naa ku, o si ṣee ṣe ko jẹ nipasẹ majele ti wọn n pe ni Sniper, to mu ni.
O ni ṣugbọn esi idanwo rẹ to wa lakọsile nileewe yii ko sọ pe Deborah kuna ninu idanwo kankan, ohun ti wọn kọ siwaju esi rẹ ni ‘Passed’ iyẹn ni pe o yege, yoo si ba awọn ẹlẹgbẹ rẹ ṣe ayẹyẹ aṣepari ninu oṣu kọkanla ti eto naa yoo waye.
Odubela sọ pe pẹlu esi daadaa ti akẹkọọ to ṣetan lẹka ẹkọ agba naa ni, ko si idi kan fun un lati mu majele nitori esi idanwo.
O ni o ṣee ṣe ko ti kuna ninu idanwo nigba kan ri, ṣugbọn o ti tun un ṣe, ki i ṣe nipele aṣekagba yii. Odubẹla ni bi akẹkọọ yii ṣe gbe majele jẹ le jẹ nitori iṣoro ilera kan.
Bakan naa ni Alukoro TASUED yii tun sọ pe ki i ṣe ọgba ileewe ni Deborah ti gbe mu majele, o ni ile awọn obi rẹ n’Ijẹbu-Ode ni.
Ileewe naa ba awọn obi akẹkọọ yii kẹdun gẹgẹ bi Odubẹla ṣe wi, wọn si gba a ladura pe Ọlọrun yoo rọ wọn loju lati bọ ninu ibanujẹ iku agbalagba ọmọ naa.
Ṣe ohun to kọkọ gun ori ayelujara ni pe Deborah mu Sniper, o si ku, nitori o feeli ọkan ninu awọn idanwo aṣekagba rẹ, eyi ti ko ni i jẹ ko ba awọn ẹgbẹ rẹ yege tabi ṣe agunbanirọ.
Eyi tilẹ tun fẹsẹ mulẹ si i, nigba ti Aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ nileewe naa, Kọmureedi Rabiu Sọdiq, n kẹdun iku Deborah Ayọmikun, to si sọ ninu atẹjade to fi sita pe kawọn akẹkọọ yee gbe igbesẹ iku bi wọn ba kuna ninu idanwo, nitori iku ki i tan iṣoro ẹda, yoo wulẹ ko awọn ololufẹ ẹni to pa ara ẹ naa sinu ibanujẹ ni.
Rabiu gba awọn akẹkọọ naa nimọran, pe bi ohunkohun ba n dun wọn lọkan, ki wọn wa ẹni kan sọ ọ fun un, eyi daa ju keeyan maa da ẹmi ara ẹ legbodo lọ.
Ṣugbọn pẹlu ohun ti ileewe sọ yii, ki i ṣe nitori aiyege ninu idanwo ni ọmọbinrin naa ṣe gba ẹmi ara ẹ, ohun to tori ẹ gbe igbesẹ buruku naa ko ye ẹni kan.