Eyi lohun ti adajọ ṣe fun Iyabọ Ojo ati Lizzy Anjorin ni kootu

Monisọla Saka

Ojo alaafia lo n rọ lọwọ lagboole tiata Yoruba bayii pẹlu bi awọn oṣerebinrin meji ti ija buruku ti wa laarin wọn lati bii ọdun diẹ sẹyin ṣe ti ọwọ ija naa bọlẹ pẹlu iranlọwọ adajọ ile-ẹjọ ti wọn gbe ara wọn lọ.

O ti ṣe diẹ ti ija ti wa laarin awọn arẹwa oṣerebinrin mejeeji ọhun, iyẹn Iyabọ Ojo ati Lizzy Anjọrin, ojoojumọ ni wọn fi n bu ara wọn, ti wọn si n pe ara wọn ni oriṣiiriṣii orukọ. Ija naa si le ni opin ọdun to kọja mọ ibẹrẹ ọdun yii, o si buru debii pe niṣe ni Iyabọ Ojo gbe Lizzy lọ si kootun fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.

Idunnu ṣubu lu ayọ fawọn ololufẹ oṣerebinrin mejeeji yii, atawọn eeyan to nifẹẹ alaafia, nigba ti Adajọ Ọlabisi Akinlade, fopin si ija aarin wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Ninu ọrọ tawọn oṣere mejeeji sọ ninu fidio ti wọn gbe sori ayelujara lẹyin ti igbẹjọ kootu wa sopin, ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe adajọ ti gba awọn nimọran, leyii tawọn ri gẹgẹ bii aṣẹ, lati gba alaafia laaye, kawọn si sinmi ariwo ati ija ori afẹfẹ.

Iyabọ ni ko wọpọ ninu adajọ ti ko ni i dajọ naa lori bi ọrọ ṣe wa niwaju rẹ, amọ ti obinrin adajọ naa ṣe bii iya fun awọn mejeeji, to si rọ wọn lati jẹ ki aawọ wọn lọ s’odo lọọ mu’mi.

Bakan naa ni agbẹjọro Anjọrin, Amofin Ọlabiyi Ademọla, naa fidi ẹ mulẹ pe awọn obinrin mejeeji ti gba lati faaye gba ifẹ ati alaafia pada. O ni iwa ati iṣe iya ni obinrin adajọ naa hu pe ki wọn yee fẹdi ara wọn sita lori ayelujara.

“Iwa iya ni adajọ hu, gẹgẹ bi eeyan ṣe n ba ọmọ ẹni wi. O gba wọn nimọran, o si da mi loju pe o ti tan, nitori ẹrin ni awọn oṣere mejeeji rin jade ninu kootu”.

Anjọrin ti inu ọkọ ẹ, Alaaji Lateef Lawal, dun lọọ di mọ Iyabọ pẹlu inu didun lẹyin aṣẹ ti adajọ pa fawọn mejeeji. O ṣalaye pe inu oun dun lori ọna ti iya naa gba dajọ awọn, ati pe ti Alaaji ba le fẹ oun ati ọrẹ oun Iyabọ pọ, ko sewu. O ni ifẹ to jinlẹ to wa laarin awọn ki ija too de, naa lawọn yoo fi maa ba ara awọn lo bayii.

Tẹ o ba gbagbe, bo tilẹ jẹ pe ikunsinu ati ija wẹrẹwẹrẹ ti n lọ laarin awọn oṣere mejeeji tẹlẹ, ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun to lọ, ni ija naa gba ọna mi-in yọ nigba ti Lizzy bẹrẹ si i fi oniruuru ẹsun kan Iyabo, to si tun n pe e ni orukọ abuku kan, iyẹn, Ṣẹpẹtẹri.

Bakan naa ni Lizzy sọ pe Iyabọ mọ diẹ lara ohun to ṣokunfa iku ọkunrin olorin taka-sufee to ṣalaisi nni, Ilerioluwa Alọba ti gbogbo eeyan mọ si Mohbad, ati pe o n fi iku ọmọ naa wa okiki, ojuure awọn eeyan ati ero lori ayelujara ẹ ni. O ni Iyabọ ati ọmọ ẹ obinrin, Priscilla, jọ maa n ba ọkunrin kan naa lo pọ lasiko kan naa, nitori owo, ati pe ajọṣepọ wa laarin Naira Marley ati Iyabọ.

O tun ni Iyabọ ni mọdaru oniroyin ori ayelujara tẹnikẹni ko mọ, to n fọ ile onile, to si n ba aye awọn eeyan jẹ, ti wọn n pe ni Gistlover.

Bo tilẹ jẹ pe Lizzy ko tọka si Iyabọ pe oun loun n pe ni Ṣẹpẹtẹri, Iyabọ ko ṣai mọ, nitori yẹyẹ ati ẹsin oriṣiriṣii toun atawọn eeyan ẹ maa n fi Iyabọ ṣe loju opo ayelujara rẹ.

Ọrọ ija wọn yii lo pin awọn ololufẹ wọn si meji, ti wọn si maa n ba ẹni ti wọn n gbe fun bu ẹni keji.

Nitori awọn ẹsun yii ni Iyabọ ṣe ke si Lizzy lati jade sita, ko si tọka si oun pe oun gangan lọrọ rẹ n ba wi.

Lẹyin eyi ni Iyabọ kọwe ẹsun ta ko Lizzy, pe ko tọrọ aforiji lọwọ oun ninu iwe iroyin ilẹ wa mẹrin ọtọọtọ, ati loju opo ayelujara ẹ laarin ọjọ meje, tabi ki o fara gba owo itanran oni ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira (500,000,000). Bi Lizzy ṣe kọ lati ṣe gbogbo eyi lo mu ki Iyabọ wọ ọ lọ siwaju ile-ẹjọ giga ijọba apapọ kan lagbegbe Ikoyi, nipinlẹ Eko, amọ ti Lizzy tabi agbẹjọro rẹ ko yọju.

Ẹnu eyi ni wọn wa nigba ti fidio ibi ti wọn ti n pariwo ole goolu le Lizzy lori ninu ọja Idumọta, niluu Eko, ti bọ sita. Eyi ni Lizzy pe ni panpẹ ti Iyabọ atawọn tiẹ dẹ kalẹ foun lati le ba oun lorukọ jẹ.

Amọ ti igbẹjọ to waye lọjọ Tọsidee fopin si gbogbo rogbodiyan yii.

Bakan naa lẹ oo ranti pe laipẹ yii ni ija ọlọjọ pipẹ laarin awọn agba oṣere meji ti wọn ti n bara wọn bọ tipẹ, Yinka Quadri ati Taiwo Hassan, tawọn eeyan mọ si Ogogo pari nibi iṣile Yọmi Fabiyi.

Bẹẹ ni Wumi Toriọla ati Habibat Jinad, Wumi Toriọla ati Zainab Bakare, naa fopin si ija aarin wọn ninu ọdun yii kan naa.

Leave a Reply