Eyi lohun ti olori ileegbimọ aṣofin sọ lori baaluu tuntun ti wọn fẹẹ ra fun Tinubu

Adewale Adeoye

Olori ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, Godswill Akpabio, ti ni awọn oun aṣofin agba niluu Abuja ko mọ nnkan kan rara nipa ọkọ baaluu tuntun ti wọn fẹẹ ra fun olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Senatọ Shettima rara.

Ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, lọ sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nigba to lọọ ṣabẹwo sile Senatọ Mohammed Tahir Monguno, to jẹ ọkan pataki lara ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, to ṣẹṣẹ padanu baba rẹ laipe yii.

Akpabio ni, ‘‘Ko soootọ ninu iroyin ẹlẹjẹ naa rara pe awọn aṣofin agba niluu Abuja fọwọ si i pe ki wọn lọọ ra ọkọ baaluu tuntun fun Tinubu ati igbakeji rẹ. Igbekeyide atawọn ọta ijọba orileede yii lo wa nidii ahesọ naa. Afojusun awọn aṣofin ni lati ṣeto bi igbe aye ṣe maa dẹrun fawọn eeyan orileede yii, ti ipinnu ta a ṣe fawọn araalu si maa wa si imusẹ lo kan wa ju lọ bayii.

‘‘Mo n fi da gbogbo araalu loju pe awa  aṣofin agba ẹlẹẹkẹwaa, niluu Abuja, ko mọ nnkan kan nipa ọkọ baaluu tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fẹẹ ra fun Tinubu ati igbakeji rẹ rara, wọn tiẹ tun fi kun un pe a ni ebi ibaa maa pa awọn araalu, ko kan wa, irọ gbuu niroyin naa, mi o kuku si nile lasiko naa, ilu Zanzibar, lorileede Tanzania, lọhun-un ni mo wa, iṣẹ ọwọ awọn ọta ilu ni gbogbo ahesọ yii.

‘’Ohun ti mo le sọ ni pe ijọba n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu bayii lati je ki igbe aye idẹrun ba awọn eeyan orileede yii laipẹ jọjọ. Ẹ maa gbadura fun awọn alaṣẹ ijọba orileede yii nigba gbogbo, ki ilọsiwaju le de ba wa laipẹ’’.

 

Leave a Reply