Eyi lohun to ṣẹlẹ nibi isinku agbẹ ti awọn Fulani pa l’Ogbomọṣọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Niṣe lẹkun n pe ẹkun ran niṣẹ lagbegbe Àrojẹ, niluu Ogbomọṣọ, nigba ti wọn n sinku ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọ̀n (31) kan, Adigun Solomon Adeyẹmi, ẹni ti awọn Fulani darandaran pa laipẹ yii.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun (22), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lawọn afurasi Fulani ọlọsin maaluu kan lọọ ka ọdọmọkunrin agbẹ naa mọ inu oko baba ẹ to wa nibi ti wọn n pe ni Oke-Asa, nitosi Iwofin, nijọba ibilẹ Surulere, nipinlẹ Ọyọ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, agbẹ ọlọgbin kaṣu ati oniṣowo kòkó ni baba Ọgbẹni Adeyẹmi, labule Elémúye, nijọba ibilẹ Surulere, nipinlẹ Ọyọ. Ọpọ igba lawọn Fulani si ti da awọn maaluu lọ sinu oko baba ẹ, ti wọn si ba awọn ohun ọgbin inu ẹ jẹ.

Lọsẹ meji ṣaaju ọjọ ti wọn gbẹmi ẹ loun ati baba ẹ, Ọgbẹni Adigun, gbena woju awọn darandaran wọnyi fun biba ti wọn n ba nnkan oko wọn jẹ. Ọrọ naa dija rẹpẹtẹ laarin wọn to bẹẹ ti ọkan ninu awọn maaluu wọn fi ba iṣẹlẹ ọhun rin.

Lọjọ keji iṣẹlẹ yii lawọn Fulani fi ọlọpaa mu Ọgbẹni Adigun, wọn loun ati ọmọ rẹ da awọn ni gbese fun bi wọn ṣe pa maaluu awọn.

Lẹyin ti wọn ti fi ọlọpaa mu baba ẹ ni wọn bẹrẹ si i ṣọ Adeyẹmi funra ẹ kaakiri titi ti wọn fi mọ oko ti oun funra rẹ n da, ti wọn si lọọ gun un lọbẹ pa mọ’bẹ lọjọ buruku eṣu gbomi mu naa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan gbe e lọ sileewosan BOWEN, to wa niluu Ogbomọṣọ, fun itọju, awọn dokita ko ti i bẹrẹ si i tọju ẹ to ti dagbere faye”.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ lọkandinlọgbọn (29), oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, lawọn daradaran lọọ ka ọkunrin agbẹ kan naa, Ajihinrere Ṣẹgun Adegboyega, mọ inu oko ẹ to da sẹyinkule ile wọn labule kan lọna Ogbomọṣọ siluu Isẹyin, ti wọn si pa a bii ẹni pẹran, nitori bi oun naa ṣe kilọ fun wọn pe ki wọn yee fi maaluu wọn ba ohun ọgbin oko oun jẹ.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ni wọn sinku Adeyẹmi si itẹ oku ijọ Onitẹbọmi ti wọn n pe ni Ogbomoọṣọ Baptist Conference Cemetery, to wa laduugbo Àrojẹ, lọna Ilọrin atijọ, niluu Ogbomọṣọ.

Gbogbo awọn ara agbegbe naa ni wọn n royin oloogbe yii gẹgẹ bii oniwa tuntun bii adaba, ẹni to tẹpa mọṣẹ daadaa, to si tun jẹ ọmọlẹyin Jesu tootọ.

Leave a Reply