Adewale Adeoye
Ni bayii, ijọba ipinlẹ Eko ti fidi rẹ mulẹ pe ohun mimu ẹlẹrin-dodo Tiger-Nut tawọn araalu Eko nifẹẹ si ju lati maa mu lo ṣokunfa ajakalẹ arun kọlẹra to n ṣoro bii agbọn laarin ilu Eko bayii, wọn si ti ṣekilọ pe kawọn eeyan, paapaa ju lọ, awọn olugbe agbegbe ijọba ibilẹ idagbasoke Eti-Ọsa, jinna si ohun mimu naa lasiko yii, titi tọwọ maa fi tẹ awọn ileeṣẹ to n ṣe ayederu ohun mimu naa sita.
ALAROYE gbọ pe awọn afurasi ọdaran kan tawọn ọlọpaa n wa bayii ni wọn n ṣe ayederu ohun mimu Tiger-Nut naa sita lọna ti ko bojumu rara, eyi to si ṣokunfa iṣẹlẹ ajakale arun kọlẹra naa niluu Eko lọwọ yii.
Oludamọran pataki fun gomina lori eto ilera nipinlẹ Eko, Dokita Ogunyẹmi Kẹmi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, sọ pe iwadi nipa iṣẹlẹ ajakalẹ arun kọlẹra naa tawọn ṣe fi han pe mimu Tiger-Nut drink kan tawọn afurasi ọdaran kan ṣe sita lọpọ yanturu lo ṣokunfa iṣẹlẹ ajakalẹ arun naa niluu Eko, nitori pe ọpọ lara awọn araalu to lugbade arun kọlẹra naa lo jẹ pe lati ijọba ibilẹ Eti-Ọsa ni wọn ti wa. Eyi lo si mu kawọn ṣewadii nipa ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ laabi naa ni agbegbe ọhun, ti esi ayẹwo tijọba ṣe si fi han pe Tiger-Nut drink tawọn araalu n mu lo ṣokunfa aarun kọlẹra naa.
Atẹjade kan to fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe ‘‘Bi ajakalẹ arun bii iru eyi ba bẹ silẹ laarin ilu, awọn ẹka ileeṣẹ ijọba to ni i ṣe pẹlu eto ilera maa fori-kori, ti wọn aa si tete wa ojutuu si wahala naa, eyi lo mu ki awọn oṣiṣẹ ajọ eleto ilera ati ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ayika nipinlẹ Eko, tete gbe igbesẹ lori ọrọ naa. Lara iwadii ta a ṣe ni pe a ri i pe ọpọ lara awọn araalu ti wọn lugbadi arun kọlẹra naa lo jẹ pe agbegbe ijọba ibilẹ Eti-Ọsa ni wọn n gbe. A lọọ ṣewadii nipa ohun to n ṣẹlẹ, abọ iwadii wa fi han pe ohun mimu Tiger-Nut lo ṣokunfa arun kọlẹra naa. Ọpọ awọn alaisan ti wọn wa sileewosan ijọba lasiko ta a n ṣewadii naa lọwọ ni wọn jẹrii si eleyii.
‘’A ti da awọn agbofinro sita pe ki wọn wa ike rẹ, iwadii wa si fi han pe ayederu ni ohun mimu naa, wọn ko gbaṣẹ lọwọ NAFDAC ko too di pe wọn ṣe e sita. Nọmba foonu nikan la ri lara ike naa, a pe nọmba naa, ṣugbọn ko sẹni to gbe e. Iwadii n lọ lọwọ lati fọwọ ofin mu awọn afurasi ọdaran gbogbo ti wọn lọwọ ninu iṣe laabi naa, ti wọn aa si foju wọn bale-ẹjọ laipẹ yii’’.