Eyi lohun to ṣẹlẹ si ọmọ Alabi Pasuma l’Amẹrika

Faith Adebọla

Ọmọ to ba mowo dele lobi rẹ yoo yin, gbogbo obi si ni wọn maa n fi ọmọ to ba ṣaṣeyọri yangan, wọn aa lo gbonjẹ fẹgbẹ, o gbawo bọ. Iru ayọ ati idunnu bẹẹ lo wa lọkan gbaju-gbaja onkọrin Fuji ilẹ wa nni, Wasiu Alabi Pasuma, Ọganla 1, lasiko yii. Eyi ko sẹyin bi ọmọ rẹ ọkunrin, Jibọla Ọdẹtọla to jọ ọ bii imumu, ṣe pari ẹkọ rẹ nileewe girama kan niluu oyinbo, Harlan Community Academy, to wa ni Amẹrika.

Ki i ṣe pe ọmọkunrin yii pari ẹkọ rẹ ṣakala bẹẹ o, o kawe yii doju ami ni debii pe oun lo ṣe daadaa ju ninu awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ kẹkọọ-jade, wọn si fi ami-ẹyẹ gẹgẹ bii akẹkọọ to ṣe daadaa ju lọ nileewe naa fun saa ikẹkọọ wọn da a lọla. Bẹẹ lawọn alaṣẹ ileewe naa si kan saara si i.

Ṣe inu ẹni ki i dun ka pa a mọra, Baa-Wasi, iyẹn Pasuma funra ẹ, lo fi idunnu rẹ yii han lori ẹrọ ayelujara, iyẹn ikanni Instagiraamu rẹ, lọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii. O loriire ile oun lasiko yii ki i ṣe ẹyọ kan rara, onibeji ni, tori bi ọmọ oun, ẹjẹ oun gan-gan, ṣe n gba ami-ẹyẹ akẹkọọ to tayọ ju lọ, to mọwe ju lọ laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ, lopin saa ẹkọ rẹ nileewe girama ọhun, bẹẹ lawọn ajọ ẹlẹyinju aanu kan tun fi ẹbun owo to ju ẹgbẹrun lọna irinwo dọla ta ọmọ naa lọrẹ, wọn fun un ni anfaani ẹkọ-ọfẹ, eyi ti wọn n pe ni schoolarship loriṣiiriṣii.

Ninu ọrọ idunnu tọmọ yii kọ si baba rẹ, eyi ti baba naa ṣafihan rẹ lori ikanni rẹ, o ni:
“Ọpẹ o, nigbẹyin-gbẹyin! Ipele oriire to kan ni mo n lọ bayii. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba, Mama mi, Baba mi, ẹgbọn mi (sista ẹ), ati gbogbo ẹyin eeyan tẹ ẹ ran mi lọwọ lojuna irinajo yii. Mo ti gba ẹbun ẹkọ-ọfẹ towo rẹ ju ẹgbẹrun lọna irinwo dọla lọ, bẹẹ ni wọn tun fun mi lawọn anfaani lati wọle sawọn orileede bii marun-un, ki n si kawe ọfẹ lawọn ileewe to ju ogun lọ.

Ipo kin-in-ni ni wọn to mi si nileewe wa, mo wa lara awọn ti esi idanwo rẹ dara ju lọ, pẹlu ami 4.20 GPA ti mo mu. Wọn fun mi lami-ẹyẹ UIC Honours College. Alhamudulilah! O ya, ipele to kan da, oke oke lemi n lọ o…”

Bẹẹ lọmọkunrin yii sọ, to si fi fọto iwe ẹri tileewe naa fun un ati awọọdu rẹ sibẹ.

Gbogbo awọn ololufẹ Baa-Wasi ni wọn ti n ki i kuu oriire aṣeyọri ọmọ rẹ yii, ti wọn si n rọ ọ lati tubọ mojuto ọmọ naa, tori ogo ọjọ-ọla lọmọ ọhun maa jẹ. Wọn ṣadura fun Jibọla kekere fun bo ṣe jẹ apẹẹrẹ atata ati aridunnu ọmọ to ṣee mu yangan.

Wọn ni inu awọn dun si Paso, tori ogun rere lo n fi silẹ fawọn ọmọ rẹ yii, o ṣetan, ọmọ ẹni lọla ẹni.

Leave a Reply