Eyi lohun to yẹ kẹ ẹ mọ nipa Adeniyi, ọga agba ileeṣẹ kọsitọọmu tuntun

Faith Adebọla

Ọkan lara awọn ti Aarẹ ana, Muhammadu Buhari, fi oye, Member of the Federal Republic, MFR, da lọla lọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni Ọgbẹni Bashir Adewale Adeniyi, ọjafafa ati eekan nileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa, Nigeria Customs Service (NCS), ni.

Oun ni Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣẹṣẹ yan sipo ọga agba patapata, iyẹn Comptroller General, fun ileeṣẹ kọsitọọmu lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

Ṣaaju iyansipo rẹ, ọkunrin yii lo wa nipo igbakeji ọga agba patapata awọn aṣọbode, oun lo si n dari ẹka ti wọn ti n ṣewadii ijinlẹ nipa ọgbọn-inu ati ilana ofin ileeṣẹ kọsitọọmu (Strategic Research and Policy) lolu-ileeṣẹ wọn to wa l’Abuja.

O ti le lọgbọn ọdun ti ọmọ bibi ilu Modakẹkẹ, nipinlẹ Ọṣun, yii ti wa lẹnu iṣẹ aṣọbode. Eyi to le lọdun mẹẹẹdogun ninu asiko naa lo fi wa nipo Alukoro fun ileeṣẹ ọhun, lati oṣu Kẹfa, ọdun 2003, ni wọn ti yan sipo agbẹnusọ ileeṣẹ Kọsitọọmu, ko si kuro nipo naa titi di oṣu Kin-in-ni, ọdun 2017, to gba agbega sipo Igbakeji ọga yan-an-yan-an, Deputy Comptroller General (DCG), ti wọn si yi iṣẹ rẹ pada, wọn ni ko lọọ ṣolori ẹka ileeṣẹ kọsitọọmu to wa niluu Apapa, nipinlẹ Eko.

Adeniyi kawe gboye ninu imọ nipa ajọṣepọ laarin orileede kan s’omi-in (International Relations) lati Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun, lọdun 1987, o si tun gba Masitaas ninu imọ ijinlẹ ibanisọrọpọ (Communication Science) lati Universitaire Svizzera D’Italina, iyẹn fasiti kan to wa niluu Lugano, lorileede Switzerland, loṣu Kọkanla, ọdun 2013.

Asiko kan torukọ oṣiṣẹ ọba yii hande gidi nigba to ko awọn ọmọọṣẹ rẹ kan sodi, ti wọn si mu awọn ti wọn fẹẹ ko obitibiti owo ilẹ okeere, miliọnu mẹjọ dọla, ($8.07 million) gba ọna ẹyin kan ti wọn n pe ni E-Wing wọ baaluu lọ siluu oyinbo, ni papakọ ofururu Murtala Mohammed to wa n’Ikẹja, l’Ekoo, wọn fẹẹ gbowo naa sọda ni Adeniyi fi mu wọn, tijọba si gbẹsẹ le owo ọhun.

Ẹyin iṣẹlẹ yii ni wọn fun un ni igbega sipo (ACG), iyẹn Assistant Comptroller General, ti wọn si ni oun ni ko lọọ maa ṣe kọmandaati wọn ni ile ẹkọṣẹ aṣọbode, Nigeria Customs Command and Staff College, to wa lagbegbe Gwagwalada, niluu Abuja.

Ọdun 2019 ni wọn yan an ṣe alakooso ẹka ileeṣẹ aṣọbode ti papakọ ofururu Murtala Mohammed, to wa n’Ikẹja ọhun.

Baale ile to niyawo atọmọ ni Adeniyi, wọn si lọkunrin naa fẹran bọọlu alafẹsẹgba gidigidi.

Leave a Reply